Home / Art / Àṣà Oòduà / A difa fun Òrúnmìlà lojo ti baba nlo sotu ife…
Kínni Ifá wí?" (What did Ifa say?)
© Adébóyè Adégbénró

A difa fun Òrúnmìlà lojo ti baba nlo sotu ife…

Ekaaro eyin eniyan mi, aojiire bi? Aku isinmi opin ose o, bi a se njade lo loni ako ni subu lase Eledumare Àse.
Laaro yi mofe fi kayefi kan to sele ni bi ojó mesan seyin ladugbo mi nilu ikorodu se idanileko laaro yi.
Gegebi mo se maa nso wípé Olorun Eledumare ni alagbara julo, iru agbara eyi o wu ka ni, boya oso niwa ni, ogbologbo aje, babalawo to gbofa to mo oyun igbin ninu ikarahun ni tabi ogbologbo aroni gbonra jigi deru oogun niwa ni, olorisa ni tabi ologboni, eyin eniyan mi ofutufete niwa niwaju Eledumare, Olorun Eledumare nikan ni oba alagbara julo, fun idi eyi gbogbo agbara ti a ba ni e jeki a maa rora lo kasi maa fi bowo fun Eledumare.

O pe ojó mesan loni nigbati kafeyi yi sele, bi mose de si adugbo ti mo ti nsise, mo jade ninu oko ayokele nigbati mo maa gbe ese seni mo nwo aso ogun ti won jo soju opopona sugbon aso náà ko jo tan, mo wa pe ikan ninu àwon omo adugbo wípé kini nkan to sele nibi laaro yi? Omokunrin yen wa sofun mi wípé seni won ri obinrin kan to wo aso ogun to nra nile wonu mosalasi nibi ti awon okunrin maa njoko si nse adura nidaji nigbati won fe lo kirun asuba, bi won se paruwo niyen, won wa lo pe arakunrin omo egbe oodua people congress kan, arakunrin naa si gbe ibon dani oni nigbati won nbeere oro lowo arabinrin náà ko le so nkankan won ni seni o nse bi eniti iye ti ra mo ninu, nigbati won wa gbe ibon ti won ni ko bo aso orun re o wa bo aso náà bi won se dana sun aso niyen, sugbon laarin iseju yen won wa omobinrin yi ti won ko ri mo, o ti “farasoko” pelu ihoho to wa, emi lo gba iyoku aso ti ko jotan naa sinu kota nitori ki awon eniyan ma baa te mole, lotito awon ara adugbo ko mo iru eni ti obinrin naa je sugbon emi mo wipe ninu awon ika aje ni to ta siagere sagbara Eledumare ti won si fi òrò enu Eledumare bawi.

Eyin eniyan mi, kosi alagbara kankan leyin Eledumare, afiti Olorun ko baiti setan lati jewo ara re fun onitohun, òrò enu Eledumare ntu bee lo si nde, fun idi eyi e jeka se jeje je o.
Òrúnmìlà naa koju iru awon isoro bayi nigbati awon eni ibi fe bayeje mo lowo, sugbon nipa oro enu Eledumare “ifa” o segun won o si raye se.
Mo maa fi ese ifá odu Osalogbe (osa elesu) se idanileko nipa iru isele to sele yi.
Ifá náà ki bayi wípé:
Omi réré
Omi rèré
A difa fun Òrúnmìlà lojo ti baba nlo sotu ife ti nlo bawon taye won se, seni iya olodogboniko ni ki Òrúnmìlà mu oun dani, Òrúnmìlà loun ko ni le mu dani nitori oun ko le jeki o doju ti oun lotu ife, iya odogboniko bere sini nbe Òrúnmìlà wipe oun koni dojuti, oni ki Òrúnmìlà jeki won bura sugbon Òrúnmìlà sofun wipe eewo oun ni ibura oni oun ko ki nbura, iya odogboniko ba bere sini soro wipe oun maa njeku, oun maa njeja, oun si maa njeran oni sugbon se Òrúnmìlà ri igi towa ninu iho okuta yen oni oun ki nje o, oni oun koni dojuti Òrúnmìlà, bi Òrúnmìlà se gba lati mulo sotu ife niyen, nigbati won de otu ife Òrúnmìlà bere sini nrubo o nsetutu lati fi tun awon nkan toti baje se, ko ti e pe rara seni iya odogboniko fo feere sode to bere sini nba otu ife je, bi okiki re se nkan sotun bee lo nkan sosi, otu ife daru o kan gogogo, gbogbo ara otu ife bere sini nparuwo le Òrúnmìlà lori wipe baba ti ba ilu won je, won ni oun lo mu alejo ajeji wolu won, won ni ko yaa lo wogbon dasi alejo re o ki o si bawon se ilu won to baje o, Òrúnmìlà ba ko oke ìpònrí re ru o so won ni seni ki Òrúnmìlà lo rubo ki o lo gbebo naa si “agbèrùn”(orita meta) Òrúnmìlà ba se bee, arubosobo ni won nse nigba kutu iwase, Òrúnmìlà lo foju pamo sibikan lati le mo nkan to maa sele, ko pe si nigbati iya odogboniko nbo lati ibi to ti lo “ró” se lo de agberun to nwo isu ati ago omi nibe, o bu serin oni Òrúnmìlà yi ma go o, oni ojo to fi eku papate oun gbeje, oni ojó to fi eja papate oun gbeje, oni ojó to fi eran papate oun gbeje oni se isu lasan lasan to wa fi rubo yi ni oun koni le je, bi o se mu isu niyen, o bu isu je wau nigba kinni o buje nigba keji, igba to maa buje nigba keta ko mo wipe egungun eran wa ninu isu ti oun buje bi o se ni ki oun gbemi seni egungun eran ha lona ofun ko wale gbe isu min mo, o bere sini nse hòò, bi esu se jade si niyen esu nise ko si omi ni Òrúnmìlà jade sita oni omi wa, won gbe ago omi ti won se ifá sinu re fun iya odogboniko, o gbe omi mun gigigi, seni iya bere sini npoyi to nbi gòòrògò, Òrúnmìlà fiyere ohun bonu wípé:
O ti nsu
O ti nbi
Odogboniko
Ko seni to mogba “to ma re o”(kú)
Odogboniko
Ki oko loyun
Ki oyà (iyawo) loyun
Omi rere kenge
Ao mo eniti to maa tete bí (bimo)
Omi rere kenge
Atetebi muku tina
Omi rere kenge
Oni ni òbò a paje
Oni ni òbò a paje o
Bi ìyá odogboniko se subu lule niyen toku, ojó naa ni otu ife bere sini dara, gbogbo àwon ara otu ife bere sini njo won nyo won nyin babalawo àwon babalawo nyin ifá, ifá nyin Eledumare won ni riru ebo a maa gbeni eru atukesu a maa da ladaju nje ko pe ko jina ifá wa bawa larusegun arusegun ni a nbawo lese obarisa.
AWO KOKO TO WA NINU ESE IFA YI NI:
1. Ifá yi ki nba eniyan bura tabi munle
2. Ifa yi ki nfe obinrin pupa
3. Ifá yi ki nje isu sisun nitori eyin dindun
4. Ifa yi ki nsi agbara tabi ipo ti eni bawa lo
5. Ifá yi ki ntapa si ona Eledumare ki eni naa ma baa subu ti koni gberi mo laye.

Ni igba kan ri ni odun 2013, mose iru etutu yi fun arabinrin kan ni Ayetoro Ayobo, o si gbe etutu naa siwaju ile re lorita, lale ojo náà ni eni to nbaja ladugbo naa gbe etutu yi lo sile to si je to mun omi ifá naa si, nigba to di ojo keji won gbe lo si celestial soosi kan sugbon àwon ara celestial sofun iyawo re wipe ki o maa gbelo si ilu re, nipa to pe ojo keta ni orun gbalejo re.
Eyin eniyan mi, mose ni iwure laaro yi wipe ako ni se si ofin Olorun Eledumare, ibinu Eledumare koni ke lori wa, ayé koni fi okunkun bo igbesi ayé wa mole, gbogbo awon eni ibi ti won ndawa laamu orun yio gba alejo won ni kiakia loni aaaase.
ÀBORÚ ÀBOYÈ OOO.

Continue after the page break for The English Version

About ayangalu

Viral Video

Support Ooduarere

SUPPORT OODUARERE
Scan QR code below to Donate Bitcoin to Ooduarere
Bitcoin address:
1FN2hvx5tGG7PisyzzDoypdX37TeWa9uwb
x

Check Also

Ìká Méjì ika meji

Ìká Méjì.

Ifa foresees a lot of Ire for the person this Odu is revealed to. He/she needs to offer Ebo so that Ase can be in his/her mouth.Ifa said if this Odu was revealed to a woman that is unable to conceive, the Babalawo will need to do Isé Ifá for her very well and the woman needs to stop eating groundnut so as for her to be able to conceive.And Ifa also made it clear that this person should always ...