Ẹgbẹ ́Afẹ́nifẹ́re kọminú lórí ìwádìí ikú ọmọ Baba Faṣọranti to jẹ olori Afẹ́nifẹ́re – Odumakin
Fẹ́mi Akínṣọlá
Àwọn àgbà ní bí eyín bá n mì pẹkẹ pẹkẹ,erìgì ni kò fálẹ̀ mójúṣe rẹ̀.
Ẹgbe Afenifẹre ti fi ero wọn han lori aijafafa ajọ awọn ọlọpaa lori ẹni to pa Arabinrin Funkẹ Ọlakunrin.
Ninu atẹjade kan ti alukoro ẹgbẹ naa, Yinka Odumakin fi ṣọwọ si awọn akọroyin ni ọjọ Isinmi Osẹ yii lọrọ naa ti jẹyọ.
Wọn ni Ọlọpaa ti n fọwọ yẹpẹrẹ mu ọrọ naa bi wọn ko si ti ri ẹni to pa arabinrin naa titi di asiko yii.
Odumakin sọ pe o ti le ni osu meji bayii ti iṣẹlẹ naa ti waye, ti ko si aridaju pe ajọ Ọlọpaa ti ri ẹnikẹni mu lori ọran naa.
Bi a o ba gbagbe, arabinrin Olufunkẹ Ọlakunrin ti o jẹ ọmọ aṣiwaju ẹgbẹ Afẹnifẹre, Rauben Faṣọnranti, ni awọn agbebọn pa ni popona Ọre si ilu Eko.
Ẹni ti o jẹ aburo si oloogbe naa, Kẹhinde Faṣọnranti ti sọ tẹlẹ nigba ti iṣẹlẹ naa waye pe awọn ọlọpaa ni darandaran lo ṣeku pa arabinrin naa.
Ẹgbe naa ni ọkan ninu awọn ẹri pe Ọlọpaa ko ṣakitiyan ni pe, wọn tete yọnda ọkọ ayọkẹlẹ ti wọn pa arabinrin naa si fun ẹbi i rẹ.
Gẹgẹ bi wọn ti wi, wọn ni Ọlọpaa ko ṣe iwadii kankan lọwọ awakọ to wa arabinrin naa titi di asiko yii.
Siwaju si i, abajade ayẹwo lori bi iku naa ṣe jẹ ko i tii tẹ ẹbi naa lọwọ titi di asiko yii.
Ẹgbẹ naa wa n rọ gbogbo awọn ẹni tọrọ kan lati parọwa si ile – iṣẹ ọlọpaa ki wọn tete fi oju awọn ẹni ibi naa lede ni kiakia,ko le jẹ arikọgbọn fawọn oṣika wole ọla tó kù.