Ekaaro eyin eniyan mi, aojiire bi? Aku amojuba osù tuntun òkudù yi, osù tuntun náà yio sanwa sowo, somo ati si aiku baale orò o, mosi tun fi asiko yi ki gbogbo awa onisese lagbaye wípé aku odun bara mi agbonmiregun kaakiri agbaye, bi a se se odun yi ao tun se ti eemin ninu ire gbogbo o àse.
E jeki a fi odu ifá mimo osa alawure yi se iwure ti ibere osù tuntun yi.
Ifá náà ki bayi wípé:
Liili eye òkun
Liili eye òsà
A difa fun Òrúnmìlà baba felo joye atáyése won ni ko karaale ebo ni ki o wa se, obi meji…. Òrúnmìlà kabomora o rubo won se sise ifá fun, lati igba náà ni Òrúnmìlà ti bere sini ntayese, baba wa njo o nyo o nyin awo àwon babalawo nyin ifá, ifá nyin Eledumare, oni riru ebo a maa gbeni eru atukesu a maa da ladaju nje kee pe kee jina ifá wa bami ni jèbútú ire nje jèbútú ire ni a nbawo lese obarisa.
Eyin eniyan mi, mose ni iwure laaro yi wípé Òrúnmìlà yio tun aye wa se o, gbogbo isoro ti a nkoju yio di nkan igbagbe ninu osù tuntun yi, ao rije ao rimun losu yi, gbogbo oke isoro wa yio di petele lase Eledumare aaaase.
ÀBORÚ ÀBOYÈ OOO.
English Version
Continue after the page break