Alágbára ayé,alágbára ayé,a sè a ṣẹ̀ má lù kan, Ọlọ́run o tíì da sí dúníyàn .Bí nǹkan se n lọ yìí, Donald Trump ni Ààrẹ orílẹ̀èdè Amẹ́ríkà kẹta nínú ìtàn tí ọ̀bẹ yóó bá ń dìí láti ọ̀dọ̀ àwọn Ilé aṣojú-ṣòfin lórílẹ̀-èdè náà.
Ìgbésẹ̀ yìí ti wá sọ ọ́ di kannakánná na ọmọ ẹ̀gà bayii nígbà tí ìjíròrò láti buwọ́lu ìyọnípò náà bá wáyé ní Ilé aṣòfin àgbà níbẹ̀.
Ẹ̀sùn méjì tó dá lórí àsìlò ipo, ati ṣiṣe idiwo fún iṣẹ́ Ilé aṣòfin-ni wọ́n fi kan Ààrẹ Donald Trump .
Ìdìbò lórí ẹ̀sùn méjì yìí kò ṣàì bá Ìlànà ẹgbẹ́ òsèlú lọ.
Gbogbo àwọn ọmọ ẹgbẹ́ òsèlú Democrats yàtọ̀ sí méjì ló dìbò fún yíyọ Trump nípò, bẹ́ẹ̀ ni àwọn Republicans tó jẹ́ ẹgbẹ́ òsèlú Trump dìbò takò ó.
Wákàtí mẹ́wàá gbáko ni ìjíròrò lórí ọ̀nà tí Ìlànà ìyọnípò náà yóó gbà fi wáyé láàrin àwọn aṣòfin àgbà náà ní Amẹ́ríkà.
Ní nǹkan bíi agogo méjì àbọ̀ òru òní tó jẹ́ agogo mẹ́jọ ààbọ̀ alẹ́ lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà ni wọn buwọ́ lu ìdìbò náà.
Ẹ̀sùn àsìlò ipò tí wọ́n fi kan Ààrẹ Trump dá lórí ẹ̀sùn pé ó gbìyànjú àti fún orílẹ̀èdè Ukraine lókùn lọ́rùn kí ó leè kéde ìwádìí ọ̀kan lára àwọn alátakò rẹ̀ lẹ́gbẹ́ òsèlú Democrats, alàgbà Joe Biden.
Ẹ̀sùn kejì tó kọ́ Trump lẹ́sẹ̀ ni pé ó dí Ilé aṣòfin lọ́wọ́ iṣẹ́ nípa kíkùnà láti fọwọ́ sowọ́pọ̀ pẹ̀lú ilé náà lórí ètò ìwádìí àti yọ Àrẹ náà nípò pẹ̀lú pípàṣẹ pé kí àwọn má ṣe fara hàn jẹ́rì í níwájú Ilé náà.
Igba ó lé ọgbọ̀n, 230 àwọn aṣòfin ló dìbò kí wọ́n yọ ọ́ lórí ẹ̀sùn àsìlò ipò tí àwọn mẹ́tàdínnígba, 197 sì ta kò ó.
Igba ó lé mọ́kàndínlọ́gbọ̀n ló dìbò fún ẹ yọ Trump lábẹ́ ẹ̀sùn pé ó dí Ilé aṣòfin lọ́wọ́ tí àwọn méjìdínnígba sì ta kò ó.
Pẹ̀lú ìyọnikúrò nípò rẹ̀ yìí, Donal trump ti di ṣàwáwù kan náà pẹ̀lú àwọn Ààrẹ méjì mìíràn tó ti jẹ rí nílẹ̀ Amẹ́ríkà nínú ìtàn orílẹ̀èdè ọ̀hún-Andrew Johnson àti Bill Clinton. Èyí ti fa ìjíròrò àti ìgbẹ́jọ́ gbogbo di iwájú àwọn aṣòfin àgbà lórílẹ̀-èdè náà láti mọ̀ bóyá lóòótọ́, Trump yóó fi ipò sílẹ
Fẹ́mi Akínṣọlá