Home / Art / Àṣà Oòduà / Ifa naa ki bayi wipe: Emi ote, Iwo ote
ose ifa

Ifa naa ki bayi wipe: Emi ote, Iwo ote

Ekaaro eyin eniyan mi, aojiire bi? Aku ise ana o, a sin ku ose ifá toni, emin wa yio se pupo re laye ase.
Gegebi a se mo wípé oni ni ose ifá, e jeki a fi odù ifá mimo eji elemere yi se iwure ti aaro yi.
Ifa naa ki bayi wipe:
Emi ote
Iwo ote
Igbati ote di meji lo dododo a difa fun baba olorire malese ire igba iwase eleyi ti ori re nfojojumo ngbare sugbon ti ese mejeeji ko lo gba ire naa, won ni ko karale ebo ni ki o wa se nitori bi ori re ba tile gba ire ki ese re mejeeji naa baa le lo maa gba ire naa, obi meji…….. baba kabomora o rubo won se sise ifa fun nigbakugba ti ori baba bati wa gba ire ese re mejeeji yio wa lo gba ire naa, baba wa njo o nyo o nyin awo awon babalawo nyin ifa, ifa nyin eledumare oni nje riru ebo a maa gbeni eru arukesu a maa da ladaju nje ko pe ko jina ifa wa bami larusegun arusegun ni a nba awo lese obarisa.
Baba wa fiyere ohun bonu wipe:
Nje bi okan bayo ninu igbo a bona wa ire kasai wami wa o ire
Bi aba bu Omi sori a bese wa ire kasai wami wa o ire.
Eyin eniyan mi, mo gbaladura laaro yi wipe ire gbogbo yio maa sawari wa, ese wa mejeeji koni lodi sori wa, ao segun amubo, aseti, ijakule ati ki won ba eniyan da majemu ki won ma fise o aaaseee.
ABORU ABOYE OOO.

English Version
Continue after the page break

Send Money To Nigeria Free

About ayangalu

One comment

x

Check Also

Obì

Obì thrown for Ọ̀sẹ̀ Ifá

Looking at the image of the Obì thrown for Ọ̀sẹ̀ Ifá today, it was coincidental that someone sent a post to me on ANGER which reflects the message from Ifá on Ogbè Yọ́nú. The post :- CONTROL YOUR ANGER You cannot see your reflection in boiling water. Similarly, you cannot see the truth in a state of anger. When the waters calm, clarity comes.” A calm mind is essential to making decisions you will not regret. A mind that’s calm ...