Àwọn aláṣẹ Saudi sọ pé kò ní ín sí ìrun Asham tàbí Taraweeh, ní àwọn mọ́sálásí tó wà ní ìlú Makkah àti Medina, àyàfi tí àrùn apinni léèmí coronavirus bá ti káṣẹ̀ nílẹ̀.
Mínísita fún ọ̀rọ̀ ẹ̀sìn lórílẹ̀-èdè náà, Abdullateef Bin Abdulaziz Al-Asheikh, ló kéde èyí nínú ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nuwò kan tó ṣe pẹ̀lú Iléeṣẹ́ ìròyìn MBC kí àwọn èèyàn le gbọ́.
Ìwé Ìròyìn orílẹ̀-èdè náà kan, Saudi Gazette jábọ̀ Ìròyìn pé Mínísítà náà sọ pé “àwọn ìrun márààrún tó jẹ́ dandan tí wọ́n ti kọ́kọ́ fi òfin dè pé kò gbọdọ̀ wáyé mọ́ ní mọ́sálásí, ṣe pàtàkì ju ìrun Taraweeh lọ.
Àdúrà wa sì ni pé Allah gba àdúrà Taraweeh wa, bóyá nílé lati kí i, tàbí mọ́sálásí, èyí tí a gbàgbọ́ pé jíjìnà síra èyí ṣe pàtàkì fún ìlera gbogbo wa.”
.
Bákan náà ló sọ pé kí Allah gba ìrun Asham tí yóó wáyé nílé kálukú tàbí mọ́sálásí.
Ẹ̀wẹ̀, Al-Asheikh sọ pe “ilẹ̀ ìsìnkú ni kí gbogbo ètò ìsìnkú ó ti máa wáyé lásìkò yìí láìsí ọ̀pọ̀ ènìyàn níbẹ̀.
Ó ní kí àwọn ènìyàn tó kù ó gba àdúrà fún òkú nílé wọn.
Kò tí ì f’ojú hàn bóyá àwọn ènìyàn ó le rìnrìnàjò sílẹ̀ mímọ́ Makkah àti Medina fún Hajj lọ́dún yìí, nítorí pé ìjọba ti fòfin de ìpéjọpọ̀ ọ̀pọ̀ ènìyàn nítorí ìtànkálẹ̀ árùn apinni léèmí coronavirus.
Ènìyàn 4,462 ni Ìjọba sọ pé ó ní àrùn apinni léèmí coronavirus ní Saudi Arabia, ènìyàn 59 ló sì ti kú.
Àwọn aláṣẹ orílẹ̀-èdè Saudi Arabia ti fòfin de kíkí ìrun Asham ní àwọn mọ́sálásí tó wà níbẹ̀