Home / Art / Àṣà Oòduà / Iwure ojo ajé toni jade ninu odu mimo ogbe onigun.
aje
Olawunmi Sarafa

Iwure ojo ajé toni jade ninu odu mimo ogbe onigun.

Ekaaro eyin eniyan mi, aojiire bi? Aku isimi ana o, Olodumare yio funwa nisinmi o, bi oni se je ojo ajé ao raje sokun ao raje sede ao si raje saiku baale orò o Ase.
Iwure ojo ajé toni jade ninu odu mimo ogbe onigun.
Ifa naa ki bayi wipe:
Kúkúùndùkú
Pété ìnàkí
Egbèje àgbàdo
Àgbàdo egbèje
A difa fun won nígùnmojò omo olówó eyo lojo ti won ni ki won o rubo ki won baa le lowo lówó, obi meji, opolopo owó eyo, opolopo eka, eru eko, eru akara, igiripa obuko ati igba ewe ayajo ifa, won kabomora won rubo won se sise ifa funwon, lati igba naa ni ara ìgùnmojò ti di olowo, won rije won rimun, won wa njo won nyo won nyin awo awon babalawo nyin ifa, ifa nyin Olodumare won ni riru ebo a maa gbeni eru atukesu a maa da ladaju ko pe ko jina ifa wa bami ni jebutu ire nje jebutu ire ni a nbawo lese obarisa.
Awon ara ìgùnmojò wa fiyere ohun bonu wipe:
Ìgùn re o omo olowo eyo
Ìgùn re o omo olowo eyo oo
Olowo eyo la npègùn o.
Eyin eniyan mi, mo se ni iwure laaro yi wipe Olodumare yio pese opolopo owó ti ao fi sele aye wa pelu irorun funwa, ako ni ku sinu ebi oun ìyà, orisa ajé yio sawari enikookan wa loni o aaaseee.
ABORU ABOYE OOO.

 

English Version

Continue after the page break.

About ayangalu

Viral Video

Support Ooduarere

SUPPORT OODUARERE
Scan QR code below to Donate Bitcoin to Ooduarere
Bitcoin address:
1FN2hvx5tGG7PisyzzDoypdX37TeWa9uwb
x

Check Also

Monday (Ojo Aje)

It is Monday (Oko Aje). Another sunny day. Ice on my cake. My Melanin still dark. Watching the world through a needle eye. But all eyes on me. Like a full moon in the sky. I can sky dive, with no fear, because my landing pad is the succulent breast of Mother Earth (Ile Aiye) full and gushing with the milk of life.  I don’t walk on egg shells, because shells are for a chicks. I am a grown bird, like ...