O lè wọ sòkòtò tó tóbi, ṣùgbọ́n kò sí ààyè fún yẹ̀rì,láti sìnrúùlú …Àjọ àgùnbánirọ̀. (NYSC)
Fẹ́mi Akínṣọlá
Ọ̀gá àgbà fún àjọ àgùnbánirọ̀ lórilẹ̀-èdè Nàìjíríà, Brig. Shuaibu Ibrahim ti sàlàyé fún akọ̀ròyìn pé ààyè wà fún àgùnbánirọ̀ tó bá fẹ́ wọ sòkòtò tó tóbi láti má fí bí ẹ̀yà ara rẹ̀ ṣe rí hàn , sùgbọ́n kò sí ààyè fún yẹ̀rì.
Ó ní àwọn alásẹ lé gbójú kúrò nínú irú ìmúra bẹ́ẹ̀ sùgbọ́n kò ní fi ojúure wo ẹnikẹ́ni tó bá lọ rán síkẹ́ẹ̀tì láti fi rọ́pò sòkòtò tí wọ́n pèsè.
Èyí jẹ́ ìdáhùn sí ìdí tí wọ́n fi le àwọn àgùnbánirọ̀ méjì kan ni ìpínlẹ̀ Ebonyi lásìkò tí wọ́n dé ibi ìpàgọ́ ìlanilọ́yẹ ọlọ́sẹ́ mẹ́ta tí wọ́n máa ń ṣe fún ẹni tó bá lọ sìnrú ìlú.
Brig. Ibrahim sọ pé àra ìdí ti àwọn kò fi le gbà kí àgùnbánirọ̀ wọ síkẹ̀tì ni pé, kò le ṣe é yan bí ológun èyí tó máa ń wáyé ní gbogbo ìgbà fún ọ̀sẹ̀ mẹ́ta náà, àti pé òfin àkọsílẹ̀ ni fún ètò àgùnbánirọ̀, èyi sì máa ń jẹ́ kí wọ́n ṣe sámúsámú.
Ààye wà fún àgùnbánirọ̀ láti wọ sòkòtò labúlabú. Ọ̀gá àgbà Olùdarí ọ̀ún ní lóòtọ́ àwọn ń gbà kí wọ́n lo ìjáàbù láti yan bí ológun ṣùgbọ́n orí àti ọrùn nìkan ló ń bò.
Ètò àgùnbánirọ̀ jẹ́ kàńpá fún gbogbo ẹnikẹ́ni tó bá kàwé gboyè jáde Fásitì tàbí Pólì, tí ìwé ẹ̀rí rẹ̀ sì jẹ́ ọ̀kan pàtàkì láti fi wá iṣẹ́ lọ́jọ iwájú, èyí túmọ si pé àwọn méjì tí wọ́n lé yìí kò ní ní àǹfànì láti ṣe iṣẹ́ ìjọba lọ́jọ́ iwájú, bákan náà ni wọn kò le gba ipò Ìjọba kankan lẹ́yìn wá ọ̀la.
Ó wá fi kún pé ààye wà fún àwọn méjèèjì láti padà wá tí wọ́n bá setán láti tẹ̀lé ìlànà tí àjọ àgùnbánirọ̀ là sílẹ̀.
Kìí ṣe ìgbà àkọ́kọ́ rèé tí irú èyí má a ṣẹlẹ̀, ní ọdún 2018, wọ́n lé Tolulope Ekundayọ kúrò ní ọgbà agùnbánirọ̀ Sahgamu fún ìdí kan náà.
Ọ̀pọ̀ àwọn ọmọ Nàìjíríà lórí àtẹ̀jíṣẹ́ twitter ti wá kéde pé níwọ̀n ìgbà ti wọ́n bá ti ń gba mùsùlùmi láàyè láti wọ ìjáàbù nítorí ẹ̀sìn, ó pọn dandan láti gba àwọn oní síkẹ̀tì náà láàyè nítorí ó lòdì sí ẹ̀sìn wọn náà ni.
Àwọn agùnbánirọ̀ méjì ni wọ́n ti fọwọ́ òsì júwe ilé fún nítorí wọ́n kọ̀ láti wọ sòkòtò tí wọ́n pèsè fún wọn ní ìpàgọ́ ìlanilọ́yẹ ọlọ́sẹ̀ mẹ́ta ní ìpínlẹ̀ Ebonyi.
Àwọn obìnrin méjì ọ̀ún ṣàlàyé pé sòkòtò wíwọ̀ lòdì sí ẹ̀sìn wọn, tí wọ́n sì kọ̀ láti wọ̀ọ́.
Nínú àlàyé tí àwọn obìnrin àgùnbánirọ̀ náà ṣe, won sọ pé nítorí ìgbàgbọ́ ló jẹ́ kí àwọn wọ síkẹ́ẹ̀tì dípò sòkòtò tó jẹ́ àlàkalẹ̀ àjọ NYSC.
Alukoro fún àjọ NYSC ní ìpínlẹ̀ Ebonyi, Ngozi Ukwuoma ṣàlàyé pé olùdarí ìpàgọ́, Isu Josephine rí àwọn méjéèjì nígbà tó ń sàbẹ̀wò.
Olùdarí náà ni ó fi orúkọ àwọn méjéèjì léde, Okafor Love pẹ̀lú nọńbà ìdánimọ̀ EB/19C/0523 àti Odiji Oritsetsolaye EB/19C/0530.
Ní kété tí wọ́n mú wọn ni àwọn àgùnbánirọ̀ náà ti ṣàlàyé pé, àwọn kò le wọ sòkòtò funfun pélébé tí àjọ náà fún wọn nítorí pé kò bá ìgbàgbọ́ àwọn mu láti wọ̀ọ́.
Gbogbo akitiyan aláṣẹ àti adarí àjọ náà láti mú wọn rí ìdí tí ó fi yẹ fún wọn láti wọ sòkòtò náà ló já sí pàbó.
Kété ni ilé ẹjọ́ tí ó wà fún àwọn agùnbánirọ̀ ní ìpàgọ́ náà dáwọn lẹ́bi títàpá sófin àti fífi ọwọ́ pa idà àlàkalẹ̀ àjọ NYSC lójú ti wọn sì fi ọwọ́ òsì júwe ilé fún wọn lẹ́yìn ọ̀ rẹyìn