Home / Art / Àṣà Oòduà / Odu Ifa Irosun Ika/Oromosunka
ori ifa verse

Odu Ifa Irosun Ika/Oromosunka

| | |
| |
| | | |
| | | |

Ekaaro eyin eniyan mi, aojiire bi? Aku ise ana, a sin ku isimi oni emin wa yio se pupo re laye ninu alaafia ara o ase.
Odu ifa IROSUN IKA/OROMOSUNKA lo gate laaro yi, ifa yi gba akapo ti odu ifa yi ba jade si niyanju wipe ki lo bo ifa daradara ki o ma baa ri Ogun(war) inira ati aisan, odu ifa yi si tun gba niyanju wipe ifa kan nbe ni sakani re to ti pe ti won ti bo ifa naa mo, ifa naa ti di papo pelu awon idoti, ifa ni ki won lo we kan si bo ifa naa nitori ki ajalu aburu ma baa jalu eni to ni tabi ilu naa.

 
Ifa naa ki bayi wipe: Oromosunka oromosungede agbe nrele ijero koko ni agbe ndun a difa fun won lode ijero-ekiti nibiti won ti fi ikin modi, won ni ki won karale ebo ni ki won wa se nitori ki won o ma baa rogun inira ati aisan, ki won baa le maa jaye irorun, obi meji, eku emon, eja aro gbigbe, igbin, agbebo adiye ati igba ewe ayajo ifa, won kabomora won rubo won si se sise ifa fun won, lati igba naa ni won ko ti jaye inira lode ijero-ekiti mo beeni aisan buburu ko kolu won, won wa njo won nyo won nyin awo awon awo nyin ifa, ifa nyin eledumare oni nje riru ebo a maa gbeni eru arukesu a maa da ladaju ko pe ko jina ifa wa bami larusegun arusegun ni a nba awo lese obarisa.
Eyin eniyan mi, mo gbaladura laaro yi wipe ako ni jaye inira nigbesi aye wa, ako ni rogun aisan buburu aisan koni fi ile wa se ibugbe, ao bori gbogbo isoro wa ninu ose yi, Orunmila(B.A) yio gbo adura wa o aaaseee.
ABORU ABOYE OOO.

 

English Version: 

Good morning my people, how was your night? Hope it was wonderfully enjoyed, wishing you all happy Sunday may our eyes witness many more on the earth in a sound and steady health amen.
It is IROSUN EKA/OROMOSUNKA corpus that revealed this morning, ifa advised whoever this corpus revealed out for that he/she should feed oke iponri(ifa) very well so that he/she would never experience hardship and chronic sickness. Also this corpus was talking about one particular ifa that have been abandoned for a while in which it had stick together, ifa advised the owner or maybe community to wash and feed the ifa quickly in order to avoid sudden tragedy.
Hear what the corpus said: Oromosunka oromosungede agbe nrele ijero koko ni agbe ndun it cast divined for them in ijero-ekiti where they were using spiritual palm nuts to build boundary, they were advised to offer sacrifice so that they would never experience hardship and sickness in their community, two kola nuts, brown mouse, dried cat fish, snail, hen and ifa leaves and they complied, aftermath they were enjoying peaceful life, they was neither sickness nor tragedy in the community, they started dancing and rejoicing praising priest the priests were praising ifa while ifa was praising God.
My people, I pray this morning that we shall never experience hardship in our life, a sickness will never befall us and use our home as an abode, we shall excel this new week, Orunmila we hears our prayers amen.

 

by Faniyi David Osagbami

About ayangalu

Viral Video

Support Ooduarere

SUPPORT OODUARERE
Scan QR code below to Donate Bitcoin to Ooduarere
Bitcoin address:
1FN2hvx5tGG7PisyzzDoypdX37TeWa9uwb
x

Check Also

16 Ofun Meji

Ifa: The 16 Odu Ifa & Their Meaning.

The meaning of the 16 Odu Ifa of the Ifa is based on 16 symbolic or allegorical parables contained in the 16 Core Chapters or Principles that form the basis of the Ifá, a system of divination of the Yoruba people of Nigeria. The Grand Priest of Ifa, the Babalawo or Iyanifas are the Priests and Priestesses of the Ifa Oracle that receive and decode the meaning of the Divine Messages contained in the Odu Ifa Parables that are transmitted ...