Home / Art / Àṣà Oòduà / Odu Ifa Iwure Toni Ki Bayi Wipe…
opn ifa

Odu Ifa Iwure Toni Ki Bayi Wipe…

Ekaaro eyin eniyan mi, aojiire bi? Aku ise ana o, oni a sanwa sire gbogbo o ase.
Odu ifa iwure toni ki bayi wipe:
Òkan fìkìkìkì babalawo oladeji difa fun oladeji eyiti won nfojojumo njuwe re fun iku, won ni ko karale ebo ni ki o wa se, obi meji, eyin adiye…….. Oladeji kabomora o rubo won se sise ifa fun bi oladeji se bo lowo iku, arun, ofo, ati gbogbo ajogun ibi niyen ti imoran ota kose lori re o wa njo o nyo o nyin awo awon awo nyin ifa, ifa nyin eledumare oni riru ebo a maa gbeni eru arukesu a maa da ladaju ko pe ko jina ifa wa bami larusegun arusegun ni a nba awo lese obarisa.
Oladeji wa fiyere ohun bonu wipe:
Nje bi e foso yin pemi emi koni je
Eyin eye o ki ndeye lohun eyin eye
Bi e fàjé yin pemi emi koni je
Eyin eye o ki ndeye lohun eyin eye
Bi e fi asasi yin pemi emi koni je
Eyin eye o ki ndeye lohun eyin eye.
Eyin eniyan mi, mo gbaladura laaro yi wipe ako ni bawon je ipe iku, arun, ejó, ofo ati gbogbo ipe ajogun ibi, imoran ota koni se lori wa o aaaseee.
ABORU ABOYE OOO.

 

 

English Version:

continue after the page break

About ayangalu

Viral Video

Support Ooduarere

SUPPORT OODUARERE
Scan QR code below to Donate Bitcoin to Ooduarere
Bitcoin address:
1FN2hvx5tGG7PisyzzDoypdX37TeWa9uwb
x

Check Also

16 Ofun Meji

Ifa: The 16 Odu Ifa & Their Meaning.

The meaning of the 16 Odu Ifa of the Ifa is based on 16 symbolic or allegorical parables contained in the 16 Core Chapters or Principles that form the basis of the Ifá, a system of divination of the Yoruba people of Nigeria. The Grand Priest of Ifa, the Babalawo or Iyanifas are the Priests and Priestesses of the Ifa Oracle that receive and decode the meaning of the Divine Messages contained in the Odu Ifa Parables that are transmitted ...