Home / Art / Àṣà Oòduà / Odu Owonrin Alakuko/Irete
ifa boy

Odu Owonrin Alakuko/Irete

| | |
| | |
| | |
|   |

Ekaaro eyin eniyan mi, aojiire bi? Aku ise ana o, a sin ku imura toni o, mo gbaladura laaro yi wipe eledumare yio mu gbogbo nkan to ndena ire gbogbo wa kuro loju ona loni, enu wa kosi ni pawa ko ni ranwa lo si orun osan gangan o ase.
Ifa naa ki bayi wipe: owonrin reterete a difa Orunmila a bu fun akuko adiye eyiti nse Omo ikofa re lojo ti won nsawo lo sona to jin gborogodo bi ojo, nigbati won dele alara won difa nile alara odu to hu jade ni owonrin irete sugbon akuko adiye ko mo oruko odu naa lo ba beere lowo Orunmila wipe baba ejowo kini oruko odu ifa to jade yi? Orunmila wa sofun wipe owonrin irete ni, oni sugbon enikeni ko gbudo gbo oruko odu ti won da nita o akuko adiye loun ti gbo, won kuro nile alara won lo sode ona oke ijero won tun difa fun alajero odu ifa owonrin irete yi naa lo tun jade, akuko adiye tun beere lowo Orunmila wipe baba kin tun ni oruko odu ifa to jade yi?

 

Orunmila tun da lohun wipe owonrin irete naa lo tun jade o si tun kilo fun wipe won ko ki nso nita o akuko adiye ni oun ti gbo, won kuro lode ijero won lo sile owa orangun aga beeni won tun difa odu kan naa yi lo tun jade bee sini akuko adiye se tun beere ti Orunmila si salaye fun, nigbati won kuro nibe ti won npada lo sile won ba gba inu oja ejigbomekun ni akuko adiye ba tun beere lowo Orunmila wipe baba ejowo oun ti gbagbe oruko odun ti won da nile awon olofin yen ni Orunmila ba so oruko naa si leti kelekele nitori eewo ni won ko gbudo kifa ninu oja ejigbomekun seni akuko adiye ba bere saruwo pipa to nsope; won ti da owonrin reterete! owonrin reterete!

 

Bi inu se bi Orunmila niyen wipe laduru ikilo toun fun iwo akuko adiye to tun wa papa paruwo odu yi ninu oja bi Orunmila se mu ori akuko adiye to fatu fai niyen to si fori akuko naa fole sinu oja ejigbomekun, won ni ki won maa tu ifa da won ni akii ntufada mo alawo laa maa yin ifa, ifa laa maa yin eledumare. Bi enu akuko adiye se ran lo sorun ojiji niyen o.
Ifa kiki ninu oja si je eewo nitori ki oja naa ma baa tuka laipe ojo.
Eyin eniyan mi, mo gbaladura laaro yi wipe enu wa koni ran wa lo sorun ojiji, ako ni si oro so, oro ti a maa so ti won maa be ori wa danu lojiji ako ni bawon so o, enikeni to ba si so wipe oun yio tu asiri wa sita ni gbangba Orunmila yio fi onitohun se etutu ni o aaaseee.
ABORU ABOYE OOO

 

English Version

Good morning my people, how was your night? Hope it was great, I pray this morning that all the hindrances that blocked the road of our success and prosperity shall be wipe away today and our mouths will not lead us to the path of destruction by the power of almighty God ase.
It is OWONRIN ALAKUKO/IRETE corpus that revealed this morning, ifa advised whoever this corpus revealed out for that he/she should not be too garrulous, he/she should have secrecy in order to avoid a sudden death by revealing a matter that suppose to be a secret publicly and ifa warned us to know the kind of person we will be going out with, so that they won’t revealing our secret matter to the people anyhow.
Hear what the corpus said: Owonrin reterete it cast divined for Orunmila and rooster his apprentice when they were going on a long journey for divination, when they reached the palace of alara, they casted divination and the corpus that revealed out was owonrin irete a rooster didn’t know the symbol that was casted and he asked from Orunmila , and Orunmila told rooster that it was owonrin irete but he shouldn’t say it publicly because it is a forbidden, they left there to ajero palace to cast divination too and the same corpus was also revealed, a rooster also asked again the type of corpus that was casted and Orunmila told him again that it was owonrin irete too, after they left ajero palace they went to owa orangun aga place to cast divination also, and same corpus also revealed out and rooster also asked the symbol of the corpus again from Orunmila and he(orunmila) told him that it is also owonrin irete and he warned him again that nobody should hear the name of this corpus anywhere and rooster agreed, when they left owa orangun aga palace they were heading home and they pass through the road of ejigbomekun market, and rooster asked Orunmila to reminded him the name of that corpus they casted today in the palace because he has forgotten it and Orunmila silently say it to his ear because it is a forbidden to chant ifa inside the market, immediately a rooster started shouting that they have casted the Owonrin reterete!! Orunmila was very angry with what the rooster did because it is also a forbidden, Orunmila removed the head of rooster and buried it inside the ejigbomekun market, that is how a rooster mouth led him to a destruction path.
My people, I pray this morning that our mouths will never lead us to a destruction path, we shall never talk where it is a forbidden to talk, we shall never use our mouths to say what will cause us a sudden death and whosoever that is planing to reveal out our secrets in a public will be offer as a sacrifice by orunmila ase.

 

Faniyi David Osagbami

About ayangalu

Viral Video

Support Ooduarere

SUPPORT OODUARERE
Scan QR code below to Donate Bitcoin to Ooduarere
Bitcoin address:
1FN2hvx5tGG7PisyzzDoypdX37TeWa9uwb
x

Check Also

16 Ofun Meji

Ifa: The 16 Odu Ifa & Their Meaning.

The meaning of the 16 Odu Ifa of the Ifa is based on 16 symbolic or allegorical parables contained in the 16 Core Chapters or Principles that form the basis of the Ifá, a system of divination of the Yoruba people of Nigeria. The Grand Priest of Ifa, the Babalawo or Iyanifas are the Priests and Priestesses of the Ifa Oracle that receive and decode the meaning of the Divine Messages contained in the Odu Ifa Parables that are transmitted ...