Home / Art / Àṣà Oòduà / Ọmọọba mẹwàá ló du òyè pẹ̀lú mi – Aláàfin Ò̩yó̩
Alaafin Oyo

Ọmọọba mẹwàá ló du òyè pẹ̀lú mi – Aláàfin Ò̩yó̩

Ọmọọba mẹwàá ló du òyè pẹ̀lú Adeyẹmi, tó sì já mọ lọ́wọ́.

Fẹ́mi Akínṣọlá

Ọlayiwọla Adeyẹmi Kẹta, ti pé ẹni ọdún mọ́kànlélọ́gọ́rín lókè eèpẹ̀ bẹ́ẹ́ ló ti lo ọdún méjìdínláàdọ́ta lórí ìtẹ́ àwọn baba ńlá rẹ̀.

Òjò ti ń pa igún bọ̀, ọjọ́ ti pẹ́ ni ọ̀rọ̀ Ọba Adeyẹmi, tori pé ojú rẹ̀ ti rí ọ̀pọ̀ ìrírí sẹ́yìn
kó tó jọba àti lẹ́yìn tó jẹ ọba tán.


kìí kúkú se ààfin ọba ni wọ́n ti wo ọba Adeyẹmi nígbà tó wà léwe, nítorí pé a rí i kà pé ó ti gbé nílùú Abẹokuta, Isẹyin àti Eko gan an rí.
Ọmọ-Ọba ni Lamidi Ọlayiwọla, nítorí inú ìdílé Ọba Alówólódù nílùú Ọyọ ni wọ́n ti bíi, bàbá àti baba-baba rẹ̀ sì jẹ Alaafin pẹ̀lú .

Orúkọ bàbá rẹ̀ ni Ọba Adeniran Adeyẹmi keji, ẹni to wa lori itẹ, ki ijọba to rọ ọ loye nitori pe o n lọwọ ninu oselu sise
Ọjọ Kẹẹdogun, osu Kẹwa ọdun 1938 ni wọn bi Lamidi Ọlayiwọla, eyi tii se ọdun mọkanlelọgọrin sẹyin

Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ọmọ ọba ni, síbẹ̀, wọ́n kò wo Lamidi kékeré nínú ààfin Ọyọ gẹ́gẹ́ bíi ọmọ ọlá, ìlú Isẹyin lẹba Ọyọ ni wọ́n ti wo dàgbà, tó sí tún lọ sílé kéú níbẹ̀
Lamidi Ọlayiwọla tún gbé ní ọ̀dọ̀ ọ Alake tilẹ̀ Ẹgba, Ọba Ọladepo Ademọla, kó tó di pé wọ́n tún rọ Alake yìí lóyè
Ó tún lọ gbé Ọlọla-binrin Kofoworọla Abayọmi ladugbo Keffi, ní Ikoyi nílùú Eko, tó si lọ sílé ẹkọ Mọda, Ọbalende Modern School
Lẹ́yìn èyí ló mórílé ileẹkọ girama St.Gregory‘s College, Ọbalende.
Ìmọ̀ nípa iṣẹ́ Amòfin ló wu Lamidi láti kọ́ nílé ẹkọ fásitì kan nílùú oyinbo, ó ku ọjọ́ méjì tí yóò tẹ ọkọ̀ létí ni wọ́n rọ bàbá rẹ̀ lóyè, tí kò sì leè lọ mọ́.

Iṣẹ́ àáyàn láàyò tí Lamidi kọ́kọ́ mú se nígbà èwe rẹ̀ ni iṣẹ́ adójútòfò (Insurance), tó sì tún jẹ́ akọsẹ-mọsẹ abẹ̀sẹ́kùbíòjò, bẹ́ẹ̀ sì ló tún máa ń se eré i ìdárayá títí di kóko yii lai naani ọjọ ori rẹ
Ki Ọlayiwọla to gun ori itẹ àwọn baba ńlá rẹ̀, iyawo meji lo ni, Olori Abibat Adeyẹmi, tí wọ́n ń pè ní iya Dodo àti Olori Rahmat Adedayọ Adeyẹmi, tí wọ́n mọ̀ sí iya Ilé kótó.


Orúkọ àkọ́bí ọmọ Ọba Adeyẹmi ni Kudirat Akọfade Erediuwa, ẹni tó ti jáde láyé báyìí. A ríi gbọ́ pé èèyàn mẹ́wàá ló du ìtẹ́ Aláàfin pẹ̀lú Lamidi Ọlayiwọla lẹ́yìn ikú u Aláàfin Bello Gbadegẹsin Ladigbolu kejì.


Lára àwọn tó du ipò náà ni Àrẹ̀mọ Sanni Gbadegẹsin, Ọmọọba Ọlanitẹ Ajagba, Ọmọọba Afọnja Ilaka, Ọmọọba Sanda Ladepo Ọranlọla àti bẹ́ẹ̀bẹ́ẹ̀ lọ.
Ọjọ́ Kẹrinla osu Kinni ọdun 1971 ni Ọba Lamidi Ọlayiwọla gun orí ìtẹ́ àwọn baba ńlá rẹ̀, tó sì di Ọba Lamidi Ọlayiwọla Adeyẹmi kẹta
Aláafin máa ń sọlá láàrín àwọn aya rẹ̀, paàpá àwọn tó jẹ́ ọ̀dọ́, tí wọ́n sì tún jẹ ojú ní gbèsè ni ọ̀dẹ̀dẹ̀, ó sì máa ń mu wọn yangàn lọ sí ọ̀pọ̀ ibi tó bá ń lọ
Lára àwọn arẹwà aya Aláàfin ni Olorì Ola, Memunat, Badrat.
Ní ẹni ọdún mọkanlelọgọrin, Ọba Adeyẹmi ní okun àti agbára tó ju tàwọn èwe mìíràn lọ, tó sì bí ìbejì ní ẹ̀ẹ̀mejì àti ìbẹta.


Onkọtan, Onpitan ati ọlọpọlọ pipe ni Alaafin, ti ko si gbagbe ọpọ itan ilẹ Yoruba ati Nàìjíríà láì náání ọjọ́ orí rẹ̀.
Lára àwọn awọn ọmọ Aláàfin tó gbajúgbajà ni Amofin Babatunde, Ọmọọba Fọlasade, Taibat, Nurudeen Adesẹgun, Akeem Adeniyi (Skimmeh), Adebayọ Fatai ati bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ.
Àwọn ọmọ Aláàfin kan ti di ipò òsèlú mú sẹ́yìn, tí àwọn mìíràn sì tún wà nípò òsèlú.
Lára wọn la ti rí Fọlasade àti Taibat tí wọ́n ti jẹ Kọmíṣọ́nnà nipinlẹ Ọyọ nígbà kan rí àti Akeem Adeniyi, tó ti jẹ alága ìjọba ìbílẹ̀ ri, tó tún lọ sílé aṣòfin àpapọ̀ ilẹ wa
Ọba Adeyẹmi gbáfẹ, o gbóge, tó sì rẹwà lọ́kùnrin.

About ayangalu

Viral Video

Support Ooduarere

SUPPORT OODUARERE
Scan QR code below to Donate Bitcoin to Ooduarere
Bitcoin address:
1FN2hvx5tGG7PisyzzDoypdX37TeWa9uwb
x

Check Also

History 101: What it takes to be a MENTALLY ENSLAVED FOOL in Your ancestral Land.

History 101: What it takes to be a MENTALLY ENSLAVED Harlequin in Your ancestral Land.

The quote for today is a page from Toyin Falola’s book, ‘Yoruba Warlords of the 19th Century’. To a lot of Yoruba Muslims. Islam means servitude to Usman Dan Fodio’s estate at Sokoto. They indulge in the same idiocy that led to the fall of the great Hausa civilization. Many Yoruba Muslims from Oyo are a dangerously brainwashed set of people that would pose future danger for the preservation of Yorubaland like their ancestors who pledged allegiance to Ilorin and ...