Home / Art / Àṣà Oòduà / Orunmila soro nipa ikin ifa !
ikin ifa

Orunmila soro nipa ikin ifa !

Ekaaro eyin eniyan mi, aojiire bi? Aku ise ana o a sin ku isimi opin ose, bi a se nwonu aye loni ako ni pare maye lara o ase.
Laaro yi mo fe fi akoko yi fesi si ibeere awon eniyan mi, ti ibeere naa lo bayi wipe; “se opele nikan ni Orunmila soro nipa re wipe ki a maa fi se iwadi nkan ni, bawo ni ti ikin ifa”?
Mo wa nfi akoko yi ndaayin lohun wipe ko ki nse opele nikan ni Orunmila sope ki a maa fi se iwadi, Orunmila soro nipa ikin ifa, nigbati Orunmila kuro nile aye to lo sidi ope agunka to ya niya buka merindinlogun latari igberaga ti abigbeyin re se si, lati igba naa ni Orunmila ti fi ikin ifa se pasiparo ara re sile aye, to fi je wipe ibiti ikin bati wa Orunmila lo wa nibe.
Siwaju si, ikin wulo pupo o si farabale daadaa lati soro ju opele lo, ikin ni a saba maa nlo lati se iwadi òrò laarin ilu tabi agbo awon eniyan to ba po, oro ikin kunju iwon ju ti opele lo, opele nsoro naa o sugbon se e mo wipe aperan nise Orunmila ni opele je, fun idi eyi o ti di dandan ki oni nkan ri isale òrò ju ti eni to maa ran lo.
E jeki a gbo nkan ti odu mimo Iwori meji yi so nipa bi ikin se da lilo fun awa olutele Orunmila.
Ifa naa ki bayi wipe:
Apa ni gboko ntana oso
Oruru ni wewu eje kanle
Ako ni dade ori
Iroko a yagbira niha
Ile ni motete ki nto wa tepon
Ope teere ereke
Ni ya siya buka merindinlogun
A difa fun Orunmila won ni baba koni bimo lotu ife, Orunmila ni igbati mo gbo mo rínwon-rínwon, Orunmila goke ijeti ile baba re won ni ki o karaale ebo ni ki o wa se, Orunmila kabomora o rubo won se sise ifa fun, nigbati Orunmila maa bi omo alakoko o bi omo ni mo bi tan ti mo fi nsara, eyiti won so ni omotara, omotara dagba o lowo o si lokiki won fi omotara joba nilu Aramoko-ekiti, won wa npe ni Alara
Nigbati Orunmila maa tun bi omo elekeji o bi oro-omo-ta-joro, eleyi ti won so ni omotajoro, omotajoro dagba o lowo o si lokiki won mu omotajoro joba nilu Ijero-ekiti, won wa npe ni Alajero
Nigbati Orunmila maa tun bi omo eleketa o bi omo ni mo bi tan ti mo funfun lara gberugberu eyiti won so ni Oloyemoyin, Oloyemoyin dagba o lowo o si lokiki won mu Oloyemoyin joba nilu Oye-ekiti, won wa npe ni Oloyemoyin
Nigbati Orunmila maa tun bi omo elekerin o bi omo ni mo bi tan ti mo gegi gegi eyiti won so ni Alakegi, Alakegi dagba o lowo o si lokiki won mu Alakegi joba nilu Ikeji ni ipinle ondo, won wa npe ni Alakeji
Nigbati Orunmila maa tun bi omo elekarun o bi omo ni mo bi tan ti mo digi ta loja ejigbomekun eyiti won so ni Onitagi olele, Onitagi dagba o lowo o si lokiki won mu Onitagi joba nilu Itaji-ekiti, won wa npe ni Onitaji
Nigbati Orunmila maa tun bi omo elekefa o bi omo ni mo bi tan ti mo nfelu nta loja ejigbomekun eyiti won so ni Elejelumope, Elejelumope dagba o lowo o si lokiki won mu Elejelu joba nilu Ijelu-ekiti(ilu esu laalu), won wa npe ni Elejelumope
Nigbati Orunmila maa tun bi omo elekeje o bi omo ni mo bi tan ti òrò mi wa gun gege eyiti won so ni Orangun, Orangun dagba o lowo o si lokiki won mu Orangun joba nilu Ila ni ipinle osun, won wa npe ni Owa orangun aga
Nigbati Orunmila maa tun bi omo elekejo o bi omo ni mo bi tan ti mo nfa owo nta loja ejigbomekun eyiti won so ni Olówò lotu ife, Olówò dagba o lowo o si lokiki won mu Olówò joba nilu Òwò ni ipinle ondo, won wa npe ni Olówò tilu òwò
Awon mejeejo ni won yan ti won si yanju pelu, seni Orunmila wa dajo odun sotu ife, odun jo osun sun àró fohun orò gbogbo omo re mejeejo lo si peju sibe won si bere sini ki baba won ni bi won se dagba si, Alara lo kókó ki Orunmila pelu emin irele to sope ” Aboru aboye baba ”
Orunmila si da lohun wipe “Aboye bosise ogbo ato asure iworiwofun”
Bee naa ni Ajero, Olóyé, Alakeji, Onitaji, Elejelumope, Owa orangun se ki baba won pelu emin irele ni kookan wipe “Aboru aboye baba” Orunmila si da olukuluku won lohun naa wipe “Aboye bosise ogbo ato asure iworiwofun”
Olówò lotu ife nikan ni ko ki Orunmila bee, Orunmila wa bii leere wipe kini oun to ri lobe to fi waro owo? Olówò wa dahun wipe iwo Orunmila sodun o sodun ko oun olowo sodun oun sodun ko
Iwo Orunmila wo bata ide oun olowo naa wo bata ide
Iwo Orunmila mu osun ide lowo oun olowo mu osun ide lowo
Iwo Orunmila de ade oun olowo naa de ade
Bee awon agba ni won sope “ori ade kan ko gbudo dobale fun ori ade keji”
Oro igberaga yi bi Orunmila ninu pupo seni baba ba fa osun re yo, bi baba se kori sidi ope agunka to ya siya bùkà merindinlogun niyen, ile aye ko wa roju mo ona aye ko suhan, eku ko ke bi eku eye ko ke bi eye, omo eniyan ko fohun bi omo eniyan, akeremodo wewu irawe awon agbaagba odo kohungbe, ato gbe mo okunrin nidi obinrin ko ri ase re mo, isu peyin ko ta agbado yomo ko gbo, a fabe sile ewure nmuuje ojo papapa kan sile adiye nsaa je, ohun búburú njalu ohun búburú ohun bùbùrù njalu ohun bùbùrù, gbogbo awon ara otu ife ni won nkigbe kiri wipe won ko ri iru eyi ri oooo, won ni igbati Orunmila wa laye iru ajalu buburu bi eleyi ko sele siwon ri, nigbati ajalu búburú yi wa po bi awon omo Orunmila se gboko alawo lo niyen won wa ni ki won karaale ebo ni ki won wa se, won ni ki won ni eku meji oluwere, eja meji abiwegbada, agbebo adiye meji abedolukeluke, obolojo igbin meji, ewure meji abamurederede ati obi meji to mori maro won rubo won ni ki won lo ree maa fi be baba won nidi ope agunka, nigbati won debe won wa bere sini fiyere ohun bonu wipe;
Ifa karele
Omo eníre
Omo eníre
Ewi nile Ado
Orisa ni Delta
Mapo elere
Moba lotun
Omo okinkin ti meyin erin nfon
Gbolajoko omo erin ti fon fikan gbuu lona alo
Omo ejo meji ti sare ganranganran lori erewe
Omo opolopo imò tu jiajia wodo
Omo aseseyo ogomo ti nfun niginigi
Omo ina joko majo ooru
Okunrin kukuruku dudu oke ijeti
Ifa karele o
Orunmila ba dawon lohun wipe oun ko pada lo sile mo
Oni ki won te owo won mejeeji siwaju o ko ikin merindinlogun sowo otun o ko ikin merindinlogun sowo osi
Oni bi won bati dele
Eni to bafe lowo eni ti e o mo bi nuhun
Eni to bafe bimo, laya, loko, kole, dagba, dogbo laye ati ire gbogbo eniti e o mo bi nuhun
Nje ifa rele olokun ko wale mo o
Eni e bari e pe ni baba.
Eyin eniyan mi, mo gbaladura laaro yi wipe ifa koni da igbona sinu aye wa o, Orunmila yio tu tiwa se, eledumare koni gbe emin igberaga wo wa bi ewu o, ifa koni binu siwa lase eledumare aaaseee.
ABORU ABOYE OOO.

 

 

English Version:
How Do We Get The Sacred Nuts (Ikin Ifa)? And The Reason Why Orunmila Descended Back To Heaven.
Happy Reading!
Good morning my people, how was your night? I wish you all happy weekend.
As we are entering into the earth today may we never disappear on earth ase.
This morning I wish to answer to my colleagues question which says, “is it only opele that Orunmila assigned to be using as a means of divination, what about ikin”?
Yeah! This is a sensible question that am expecting from intelligence people like you.
A sacred nuts are the object that Orunmila used to represent himself after descended to heaven at the bottom of agunka palm tree which have sixteen branches of head while opele is a tool that Orunmila is using for making divination while on the earth.
Ikin( sacred palm nuts) are very respective and have a brighter sight than opele, sacred nuts are best used while consulting for town or community because of his wide sighting.
Let us hear what the holy corpus of Iwori meji said.
Apa ni gboko ntana oso
Oruru ni wewu eje kanle
Ako ni dade ori
Iroko a yagbira niha
Ile ni motete ki nto wa tepon
Ope teere ereke
Ni ya siya buka merindinlogun
It cast divined for Orunmila when they said he will never give birth to any child in ife town, when I heard I laughed at them, during this time in otu ife Orunmila was unable to have child and people of otu ife were mockery him, when Orunmila consulted his divination on what he would do that will make him have child, he was advised to offer sacrifice and he complied, then Orunmila gave birth to (omo ni mo bitan ti mo fi nsara) in which we translated to omotara as first child, when omotara became popular and rich he was installed as the king of Aramoko-ekiti, and people were calling him Alara,
Orunmila gave birth to (oro omo ta joro) in which we translated to omotajoro as second child, when omotajoro became popular and rich he was installed as the king of Ijero-ekiti, and people were calling him Ajero
Orunmila gave birth to (omo ni mo bitan ti mo funfun lara gberugberu) in which we translated to Oloyemoyin as third child, when oloyemoyin became popular and rich he was installed as the king of Oye-ekiti, and people were calling him Oloyemoyin
Orunmila gave birth to (omo ni mo bitan ti mo gegi gegi) in which we translated to Alakegi as fourth child, when Alakegi became popular and rich he was installed as the king of Ikeji in ondo state, and people were calling him Alakeji
Orunmila gave birth to (omo ni mo bitan ti mo digi ta loja ejigbomekun) in which we translated to Onitagi olele as fifth child, when Onitagi became popular and rich he was installed as the king of Itaji-ekiti, and people were calling him Onitaji
Orunmila gave birth to ( omo ni mo bitan ti mo nfelu ta loja ejigbomekun) in which we translated to Elejelumope as sixth child, when Elejelumope became popular and rich he was installed as the king of Ijelu-ekiti(the home of esu laalu), and people were calling him Elejelumope
Orunmila gave birth to (omo ni mo bitan ti òrò mi wa gun gege) in which we translated to Owa orangun as seventh child, when Owa orangun became popular and rich he was installed as the king of Ila orangun in osun state, and people were calling him Owa orangun aga
Orunmila gave birth to (omo ni mo bitan ti mo nfawo ta loja ejigbomekun) in which we translated to Olówò lotu ife as last eighth child, when Olówò became popular and rich he was installed as the king of Owo land in ondo state, and people were calling him Olowo of owo
All these eighth children were popular and rich, when it is a day of Orunmila’s festival in otu ife all his children were present and line up according to their seniority, Alara as the first child said “Aboru aboye baba” with respect and honour and Orunmila replied him “Aboye bosise ogbo ato asure iworiwofun” also Ajero, Oloyemoyin, Alakeji, Onitaji, Elejelumope and Owa orangun aga also said “Aboru aboye baba” one after the other with respect and honour and Orunmila replied them “Aboye bosise ogbo ato asure iworiwofun” when it is the turn of their last born Olowo lotu ife he didn’t say anything, then Orunmila asked him that why you didn’t greet me like your elders did? Olowo said father you put on Òdùn cloth I also did, you tied òdùn round your body I also did, you wear brass shoe and I also did, you hold brass staff and I also did, you wear crown and I also did, then an elderly people said that; One king should never portray to another king, when Orunmila heard this word of arrogance from his last born he was very angry, he removed his staff and went to the bottom of sacred palm tree that have sixteen branches of head, since then otu ife was rough and tough, there was a famine, calamity, chaos, infertility, dryness, and suffering all over and people were shouting angrily around community that during the time of Orunmila there were nothing like these, everything was going smoothly and perfectly, when this inconveniences were too much, all the eighth children of Orunmila went for consultation on what they can use to plead to their father that will make him return back home, and they were advised to offer two mouses, two fishes, two goats, two hens and two snails to go and use them to beg their father at the bottom of sacred palm tree that have sixteen branches of head and they complied, when they reached there, they started singing that;
Ifa let us go back home
The son of eníre
The son of enìre
The king of Ado-ekiti town
The deity in delta
The son of tusk that blow the tooth of elephant
The son of two snakes that were running perfectly on the leafs
The son of plenty of palm leafs that waving seriously at the river
The son of new palm frond that white perfectly
The mapo of ijelu
The moba of otun
A short black complexion man of oke ijeti
Ifa let us go back home
Orunmila said am not returning back home, he told them to spread their hands in the front and he put sixteen sacred nuts in the right hand and he put sixteen sacred nuts in the left hand Orunmila told them, when you reach house if you want to have money that is the person you need to consult
If you want to have wife/husband that is the person you need to consult
If you want to have children, long life and all goodnesses that is the person you need to consult
Ifa has gone to olokun’s house without returning back home
Whosoever you see just call him father.
My people, I pray this morning that we shall never experience the aggrieve of Orunmila, our lives will never polluted, may God in his infinite mercy never wear an arrogant cloth in our body ase.

 

Faniyi David Osagbami

About ayangalu

Viral Video

Support Ooduarere

SUPPORT OODUARERE
Scan QR code below to Donate Bitcoin to Ooduarere
Bitcoin address:
1FN2hvx5tGG7PisyzzDoypdX37TeWa9uwb
x

Check Also

16 Ofun Meji

Ifa: The 16 Odu Ifa & Their Meaning.

The meaning of the 16 Odu Ifa of the Ifa is based on 16 symbolic or allegorical parables contained in the 16 Core Chapters or Principles that form the basis of the Ifá, a system of divination of the Yoruba people of Nigeria. The Grand Priest of Ifa, the Babalawo or Iyanifas are the Priests and Priestesses of the Ifa Oracle that receive and decode the meaning of the Divine Messages contained in the Odu Ifa Parables that are transmitted ...