Osinbajo wọ́gilé ìrìn-àjò rẹ̀ lẹ́yìn tí ọ̀kan lára ẹ̀ṣọ́ rẹ̀ kú lọ́nà pápákọ̀ òfurufú
Ọ̀kan lára àwọn ẹ̀ṣọ́ ìgbákejì Ààrẹ, Ọ̀jọ̀gbọ́n Yemi Osinbajo sàgbákò ikú ójijì nínú ìjàmbá alùpùpù lọ́jọ́ Ẹtì.
Ali Gómìnà, tó jẹ́ ọlọ́pàá rìpẹ́tọ̀ gbẹ́mì ín mì nínú ìjàmbá náà tó ṣẹlẹ̀ lọ́nà pápákọ̀ òfurufú Nnamdi Azikiwe nílùú Abuja.
Gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ tí olùdámọ̀ràn ìgbákejì Ààrẹ lórí ọ̀rọ̀ ìròyìn, Laolu Akande sọ, Gómìnà wà lára àwọn ẹ̀ṣọ tó ń sin ìgbákejì Ààrẹ lọ nígbà tí ìṣẹ̀lẹ̀ burúkú náà ṣẹlẹ̀.
Ọ̀gbẹ́ni Akande ṣàlàyé pé ìgbákejì Ààrẹ ti wọ́gilé ìrìn-àjò tó fẹ́ rìn náà lẹ́yìn ikú ọlọ́pàá ọ̀ún tó jẹ́ ẹni ọdún mẹ́ẹ̀dọ́gbọ̀n.
Ọ̀jọ̀gbọ́n Osinbajo sàpèjúwe olóògbé náà gẹ́gẹ́ bí ẹni tó jára mọ́ iṣẹ́, tó ṣì ṣe é fi ọkàn tán .
Gómìnà fi ìyàwó àtàwọn ọmọ sílẹ̀ lọ, olùdámọ̀ràn ìgbákejì Ààrẹ gbàdúrà pé kí Elédùwà tẹ ẹ si afẹ́fẹ́ rere.
Fẹ́mi Akínṣọlá
iroyinowuro