Arun iba buruku kan n da yanpon- yanrin sile bayii ni ile-ise awon obinrin (Queens college) to wa ni ilu Eko.
Ironu ti dori awon agba kodo ni ipinle Eko bayii paapaa julo fun gbogbo awon to lomo nibe.
Ile-iwe yii loruko to dara lati odun to ti pe. Ibe ni opo awon omo eniyan pataki lawujo n fi omo won si ki o to di pe awon ile-iwe aladaani tu jade ni nnkan bii ogoji odun seyin.
Ko tii pe odun meta bayii ti arun omi mimu semi awon omo meta legbodo ni ile-ise naa.
Yoruba bo, won ni “eni to gunyan je to ku, ti seru ba eni to gbe isu kana”.
Isele odun keta seyin lo mu ki opo obi tete lo maa ko awon omo won bi won se gbo pe arun kan tun ti sele ni ile-iwe naa.
Omo ti ko din ni egberun lo ti kuro ni ile-iwe naa titi di asiko ti a n ko iroyin yii jo.
Onikaluku awon obi yii lo si n mu awon omo naa gba ile-iwosan lo.
Gbogbo awon obi ti o wa loke okun gan-an lo ti n ranse sile ki awon ojulumo won le tete ba won se amojuto awon omo won.
Orisiirisii ipade lo ti n lo lowo bayii laarin awon egbe obi ati oluko ile-iwe naa lati le wa ona abayo si isele naa.