Atijo tun padanu nile ejo to ga ju
Lati owo
Yinka Alabi
Ile-ejo to ga ju lo ni orileede yii ti se idajo lori ejo ti oludije dupo Aare ni abe egbe oselu PDP, Alhaji Atiku Abubakar.
Ile-ejo ni Aare Muhammadu Buhari naa ni o jawe olubori nibi ibo Aare to waye naa.
Olori egbe oselu APC, Adams Oshiomole ni “oro omugo lo maa n yato,bakan naa ni ti ologbon ri”. O ni ile-ejo lo je ki o ye awon egbe oselu alatako mo pe ipo Aare kii se ohun ti awon omo Yahoo kan le ko jo loru. O ni orileede yii ti koja ibo “aburakadaka”.
Aare Mohammadu Buhari naa ni inu oun dun si idajo naa, oun si maa feran ki egbe oselu PDP darapo mo oun ki awon le jo gbe Naijiria de ebute ogo.
Atiku Abubakar ni inu oun ko baje pe egbe oun padanu ejo naa nile ejo giga. O ni ija ti o dara ni oun ja,ni eyi to mu ki idagbasoke ba eto oselu orileede yii.
Tagged with: Asa Oodua asa Orisa Ede Oodua iroyin