Home / Art / Àṣà Oòduà / Ladoja setan lati gba ipo gomina pada lowo Ajimobi ni kootu
ladoja

Ladoja setan lati gba ipo gomina pada lowo Ajimobi ni kootu

Ladoja ati Ajimobi: Taani ipo gomina yoo ja mo lowo ni kootu?

Oniroyin: Olayemi Olatilewa
Orisun
Oniroyin: Twitter

Nibayii, won ti kede ojo ti won yoo pari ejo, eleyii ti o je asekagba, to wa laaarin Senato Rasheed Adewolu Ladoja ati Gomina ipinle Oyo, Senato Abiola Ajimobi eleyii to da lori eto idibo gomina to waye ninu osu kerin odun yii.

Ladoja lo gbe Gomina Abiola Ajimobi lo siwaju ile ejo kotemilorun tiribuna pelu esun wi pe magomago lo kun inu eto idibo to gbe Ajimobi wole gege bi gomina ipinle naa.

Leyin akojopo iwadii ati atotonu awon igun mejeeji ti oro naa kan, Aliyu Maiyaki to je adari igbimo tiribuna naa ti kede ojo ketadinlogbon osu kewaa odun yii (27/1015, ojo Tusde) gege bi ojo ti ejo naa yoo kase nile patapata.

Ninu eto idibo to waye losu kerin odun 2015, Gomina Ajimobi ti egbe oselu APC ni ajo INEC kede wi pe o bori pelu iye ibo 327 320. Nigba ti Ladoja ti egbe oselu Accord gbenu le e pelu iye ibo 254 520.
Eto idibo yii lo so Ajimobi di gomina akoko ti yoo wole fun igba keji si ipo gomina ni ipinle Oyo.

Ti e ko ba gbagbe, lojo kinni osu kokanla odun 2006. Ile ejo da Ladoja lare, o si paalase wi pe ki won da Ladoja pada si ipo re gege bi gomina leyin igba ti awon omo ile igbimo kan pawopo lati yo lona ti ko ye gege bi gomina ipinle Oyo nigba naa.

Eleyii fi han wi pe igba akoko ko ni yii ti Ladoja, eni odun mokanlelogorin (71), yoo ma gba ijoba pada nile ejo. Nje Ladoja yoo tun ri eleyii se loteyii?

Orisun
Oniroyin Twitter

Send Money To Nigeria Free

About admin

x

Check Also

nigerian police

Họ́wù! Àgọ́ ọlọ́pàá ni wọ́n tí fọmọ odó lu èèyàn méjì pa

Họ́wù! Àgọ́ ọlọ́pàá n wọ́n tí fọmọ odó lu èèyàn méjì pa Ará kò níí tán nílé alárà láé láé. À bí kínni kí á tí wí pẹ̀lú bí èèyàn méjì ti kú lẹ́yìn tí ọlọ́pàá kan fi ọmọ odó lu ọ̀dọ́ mẹ́ta fún pé wọ́n jí adìẹ. Ẹnìkẹta, Abdulwahab Bello, nìkan ni ó yè. Ṣùgbọ́n, ó fi ara gba ọgbẹ́, tí egungun rẹ̀ sì kán, lẹ́yìn tí ọlọ́pàá náà lù wọ́n ní àgọ́ ọlọ́pàá kan ní Ìpínlẹ̀ Bauchi. Abdulwahab ...