Home / Art / Àṣà Oòduà / Ẹjẹ yóó sàn, bí Amẹ́ríkà ṣe pa olórí ọmọ ogun un wa – lran
Qasem Soleiman

Ẹjẹ yóó sàn, bí Amẹ́ríkà ṣe pa olórí ọmọ ogun un wa – lran

Ẹjẹ yóó sàn, bí Amẹ́ríkà ṣe pa olórí ọmọ ogun un wa..lran

Kójú má ríbi , gbogbo ara lòògùn rẹ̀,bó ṣe jẹ́ pé, ó ń bọ̀ ,ó ń bọ̀ , gbogbo ara ní wọ́n mú tó o.
À bí kí lọ̀rọ̀ ogun abẹ́lé kẹta “World War III”ṣe tan mọ́ ikú olórí ọmọ ogun Iran tó kú?
Àwọn ènìyàn káàkiri àgbáyé ti ń sọ̀rọ̀ lórí bí àwọn ọmọ ogun Amẹ́ríkà ṣe pa Ọ̀gágun pàtàkì kan k’órílẹ̀èdè Iran, Qasem Soleiman.

Òwúrọ̀ ọjọ́ Ẹtì ni ìròyìn jáde pé “Ààrẹ Amẹ́ríkà, Donald Trump ló pàṣẹ bí wọ́n ṣe ju àdó-olóró lù ú, 5098090550980905t ó sì mú ẹ̀mí rẹ̀ lọ.

Ohun tí ọpọ ènìyàn ń sọ lórí Twitter ni pé pípa tí wọ́n pa Ọ̀gágun náà yóó fa ogun àgbáyé kẹta.

Bí àwọn kan ṣe ń fi ọ̀rọ̀ náà ṣe nǹkan tó ń fẹ́ ìgbaradì àti amójútó tó yanrantí ni àwọn kan fi ń ṣe ẹ̀fẹ̀.

Àwọn ọmọ ogun ilẹ̀ Amẹ́ríkà ti pa Ọ̀gágun Qasem Soleiman tó jẹ́ olórí ẹgbẹ́ ogun Quds ní Iraq.

Olú iléeṣẹ́ ológun ilẹ̀ Amẹ́ríkà, “The Pentagon”, fìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé àwọn pa á “nítorí àṣẹ tí àwọn gbà láti ọ̀dọ̀ Ààrẹ.”

Inú ọkọ̀ ayọkẹlẹ kan tí wọ́n fi gbé Ọ̀gágun Soleiman ló wà ní pápákọ̀ òfurufú Baghdad, pẹ̀lú àwọn ọmọ ogun ajìjàgbara, lásìkò tí àdó olóró já lù ú láti òfurufú.

Kò sì dín ní ènìyàn márùn tó ṣeéṣe kó kú lára àwọn tí wọ́n jọ ń lọ.
Olórí tó ga jù lọ ní orílẹ̀èdè Iran, Ayatollah Ali Khamenei ti sọ pé “ìjìyà ńlá ń dúró de àwọn ọ̀daràn tó wà nídìí ìṣẹ̀lẹ̀ náà”.

Bákan náà ló tún kéde ọjọ́ mẹ́ta láti sẹ ọ̀fọ̀ àwọn tó kú.

Ọ̀kan pàtàkì ni Ọ̀gágun Soleiman nínú Ìjọba tó wà l’óde ní Iran, Ayatollah Ali Khamenei sì ni ikọ ajijagbara rẹ, Quds, n jábọ fun.

Ṣùgbọ́n, ilẹ̀ Amẹ́ríkà ti kéde Ọ̀gágun náà, àti ikọ ajijagbara Quds, gẹgẹ bi agbesunmọmi, to si tun sọ pe wọn mọ si bi ogunlọgọ awọn ọmọ ogun ilẹ Amẹrika ṣe ku.

Ìkéde kan sọ pé àwọn pa Ọ̀gágun Soleiman láti dáàbò bo àwọn ọmọ ogun Amẹ́ríkà tó wà nílẹ̀ òkèèrè.

Èyí wáyé lẹ́yìn ọjọ́ díẹ̀ tí àwọn kan tó fi ẹ̀hónú hàn kọlu iléeṣẹ́ Ìjọba Amẹ́ríkà ní Baghdad, tí àwọn àti àwọn ọmọ ogun Amẹ́ríkà sì kọlu ara wọn níbẹ̀.

Olú iléeṣẹ́ ológun Amẹ́ríkà sọ pé Ọ̀gágun Soleiman fọwọ́ sí bí wọ́n ṣe kọlu iléeṣẹ́ Amẹ́ríkà.

Ní kété tí Ìròyìn ikú Soleiman jáde, ni Ààrẹ Amẹ́ríkà, Donald Trump fi àwòrán àṣìá Amẹ́ríkà s’órí Twitter.

Femi Akínṣọlá

Iroyinowuro

About ayangalu

Viral Video

Support Ooduarere

SUPPORT OODUARERE
Scan QR code below to Donate Bitcoin to Ooduarere
Bitcoin address:
1FN2hvx5tGG7PisyzzDoypdX37TeWa9uwb
x

Check Also

martynov

New Reality