Kogi àti Bayelsa ìdìbò gómìnà gbọdọ̀ lọ nírọwọ́ rọsẹ̀.. ..Ààrẹ Buhari
Fẹ́mi Akínṣọlá
Ṣé ko ko ko là á ránfá adití,àti pé ó ń bọ̀, ó ń bọ̀,ojú ni wọ́n ń mú tó o. Èyí ló mú kí Ààrẹ orílẹ̀ yìí Muhammadu Buhari má a ké tan tan tan saájú ìdìbò gómìnà ní Ìpínlẹ̀ Kogi àti Bayelsa lọ́jọ́ Sátidé ọ̀sẹ̀ yìí, fìkìlọ̀ léde fáwọn òṣìṣẹ́ elétò ààbò láti dènà àwọn jàǹdùkú tó bá fẹ́ jí àpótí ìdìbò gbé.
Buhari nínú àtẹ̀jáde tó fi síta láti ọwọ́ olùdámọ̀ràn pàtàkì lórí ọ̀rọ̀ ìròyìn, Garba Shehu, sọ fáwọn òṣìṣẹ́ elétò ààbò pé kí wọ́n ṣiṣẹ́ wọn bí iṣẹ́, kí wọ́n rí i pé àwọn èèyàn dìbò gẹ́gẹ́ bí ẹ̀tọ́ ọ wọn.
Ààrẹ Buhari sọ pé gbogbo ọ̀nà ni káwọn ẹ̀ṣọ́ elétò ìdìbò fi dènà ẹnikẹ́ni tó bá fẹ́ jí àpótí ìdìbò gbé.
Ààrẹ ní ẹnikẹ́ni kò gbọdọ̀ dúnkokò mọ́ ẹnikẹ́ni tàbí dènà ẹnikẹ́ni láti dìbò gẹ́gẹ́ bí ẹ̀tọ́ wọn.
Bákan náà ni Ààrẹ Buhari képe àwọn olùdìbò ní ìpínlẹ̀ Bayelsa àti Kogi láti ṣe jẹ́ẹ́jẹ́ níbùdó ìdìbò, kí wọ́n sì dìbò lálàáfíà gẹ́gẹ́ bí òfin ti làá kalẹ̀.
Buhari sọ pé, ”níbi gbogbo tí ètò ìdìbò ti ń wáyé ni olùdíje kan yóó ti jáwé olúborí, tí òmíràn yóó sì fìdí rẹmi, ti Bayelsa àti Kogi kogi náà kò gbọdọ̀ yàtọ̀.”
Ààrẹ Buhari rọ àwọn olùdíje láti gba èsì ìdìbò tí yóó wáyé bí ó bá ṣe rí láì dá rògbòdìyàn sílẹ̀.
Ààrẹ ní olùdíje tí ètò ìdìbò kò bá tẹ́ lọ́rùn láṣẹ láti gba ilé ẹjọ́ lọ dípò kí ó dá wàhálà sílẹ̀.
iroyinowuro