Home / Art / Àṣà Oòduà / Ifa naa ki bayi wipe: Òkàn sá
ifa

Ifa naa ki bayi wipe: Òkàn sá

Ekaaro eyin eniyan mi, aojiire bi? Mo lero wipe gbogbo wa la sun dokan daradara aku isimi opin ose, mosi fi asiko yi ki gbogbo àwon ore mi ti won je omo leyin kristi wípé eku odun eku iyedun emin yio se pupo re laye ninu ola ati idera o Àse.
Ifá yi gba wa niyanju, tabi eni to ba bi nigbodu/itenifa niyanju wipe ki o se etutu daradara ki won si se akose ifa yi fun ki o fi sin gbere sorun owo re mejeeji ki a si tun se akose elemun fun akápò yi ki o maa mu dani fun sise adura lararo nitori ki o ma baa maa se Ogun amubo ati aseti ki gbogbo nkan to ba ndawole baa le maa yori si rere.

Ifá yi gba okunrin ti odu yi ba jade si niyanju wipe ki o se etutu naa ki o ma baa maa se amubo iyawo , ki iyawo ba le ba gbele dojo ale, ti o ba si je obinrin naa lo jade si ki o se etutu naa daradara o ki o ma baa ni isoro Oko ki won ma baa maa gbe lagbeju sile ki o ba le lade lori dojo ale re.
Ifa naa ki bayi wipe:
Òkàn sá
Èjì sá babalawo àsá dífá fun àsá lojo ti o nroko iwaje, beeni asa nse Ogun amubo o nse Ogun aseti o wa goke ijeti ile Orunmila “won gbódo wálè àgbède òrun ro” won ni ko karale ebo ni ki o se ki o ma baa maa se amubo ati aseti mo ki o baa le maa ri eran obi meji……..sile meta owo ati igba ewe ayajo ifá, àsá kabomora o rubo won ni ko gbe lo sorita meta ajaloko àsá si se bee, nigbati o dorita meta o wa nse adura si etutu ni esu odara de, o wa beere lowo asa wipe kini isoro re? Asa ni Ogun amubo ati aseti lo nba oun finra pe kosi gbogbo nkan toun ba mu ti ki nbo lowo oun, esu ba mu ikan ninu emu ti asa fi rubo yen o fi ikan si lowo otun o fi ikan si lowo osi oni kosi nkan to bati mu ti yio bo lowo re mo inu asa ba dun to ba wati ri nkan to fe gbe àsá a so wipe;
Àpasà?
maa ni o han só,
Oni òkò àsá nko?
Mani ki nbale nsanwo, lati igba náà ni àsá ti segun Ogun amubo ati aseti o wa njo o nyo o nyin awo awon babalawo nyin ifá, ifá nyin Eledumare oni riru ebo a maa gbeni eru atukesu a maa da ladaju nje ko pe ko jina ifá wa bami larusegun arusegun ni a nbawo lese obarisa.
Eyin eniyan mi, mose ni iwure laaro yi wipe ire ayé wa koni bo danu lowo wa mo, ao maa ni aseyori lori gbogbo adawole wa, gbogbo obinrin ti won nse amubo Oko yio di asegun loni e o si lade lori dojo ale yin, gbogbo okunrin ti won nse amubo iyawo won yio di alaya ni odede, ako ni sanwo ire gbogbo mo laelae, laalaa wa koni jasi asan lase Eledumare aaase.
ÀBORÚ ÀBOYÈ OOO.

 

English Version:

Continue after the page break

About ayangalu

Viral Video

Support Ooduarere

SUPPORT OODUARERE
Scan QR code below to Donate Bitcoin to Ooduarere
Bitcoin address:
1FN2hvx5tGG7PisyzzDoypdX37TeWa9uwb
x

Check Also

16 Ofun Meji

Ifa: The 16 Odu Ifa & Their Meaning.

The meaning of the 16 Odu Ifa of the Ifa is based on 16 symbolic or allegorical parables contained in the 16 Core Chapters or Principles that form the basis of the Ifá, a system of divination of the Yoruba people of Nigeria. The Grand Priest of Ifa, the Babalawo or Iyanifas are the Priests and Priestesses of the Ifa Oracle that receive and decode the meaning of the Divine Messages contained in the Odu Ifa Parables that are transmitted ...