Họ́wù! Àgọ́ ọlọ́pàá n wọ́n tí fọmọ odó lu èèyàn méjì pa
Ará kò níí tán nílé alárà láé láé. À bí kínni kí á tí wí pẹ̀lú bí èèyàn méjì ti kú lẹ́yìn tí ọlọ́pàá kan fi ọmọ odó lu ọ̀dọ́ mẹ́ta fún pé wọ́n jí adìẹ.
Ẹnìkẹta, Abdulwahab Bello, nìkan ni ó yè. Ṣùgbọ́n, ó fi ara gba ọgbẹ́, tí egungun rẹ̀ sì kán, lẹ́yìn tí ọlọ́pàá náà lù wọ́n ní àgọ́ ọlọ́pàá kan ní Ìpínlẹ̀ Bauchi.
Abdulwahab sọ pé iṣẹ́ abánikọ́lé ni òun ń ṣe, àti pé àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ ló kó adìẹ méje wá bá òun, kí òun tó tẹ̀lé wọn lọ sí ọjà láti tà á.
Lẹ́yìn náà ni àwọn ọlọ́pàá wá kó wọn, pé àwọn jí adìẹ.
Abdulwahab tẹ̀síwájú nínú ọ̀rọ̀ rẹ̀ pé níṣe ni Ọ̀gá ọlọ́pàá náà ‘DPO’ fi okun so oun, to si bẹrẹ si ni fi ọmọ odó lu oun ni ẹsẹ titi to fi kan.
Abdulwahab ni : “Lẹ́yìn náà ló bọ́ sí ẹsẹ̀ kejì, tó sì tún kán an, kó tó ó bọ sí itan.”
“Níṣe ni mo sin àwọn ọ̀rẹ́ mi lọ ta adìyẹ l’ọ́jà, kódà èmi ni mo yá wọn ni owó tí wọ́n fi wọ ọkọ̀ lọ.”
Ìyókù nǹkan tí Abduwahab sọ nìyí; Lẹ́yìn tí wọ́n ta adìẹ tán ni wọ́n tó ó dá owó mi padà. Ní kété tí wọ́n kó wa dé àgọ́ ọlọ́pàá, ni Ọ̀gá wọn sọ pé kí gbogbo wa ó dojú bolẹ̀.
Kò pẹ́ ẹ̀ ló ní kí àwọn ọlọ́pàá ó dè wá ní ìkọ̀ọ̀kan, tó sì lọ̀ ọ́ gbé ọmọ odó láti má a fi lù wá.
Abdulwahab sọ fún akọròyìn pé ọ̀rẹ́ òun Ibrahim ló kọ́kọ́ lù láyà, àti ẹ̀yìn títí tó fi dákẹ́.
“Mo kọ́kọ́ ro pé ó dákú ni, ṣùgbọ́n nǹkan tí DPO náà ń sọ ni pé “ó sàn kó o kú nítorí pé o kò wúlò fún nkànkan.”
Lẹ́yìn náà ló bọ́ s’órí ọ̀rẹ́ mi kejì, tó sì lu òun náà tó fi kú.”
Ó ní bó tilẹ̀ jẹ́ pé orí ìso ni òun wà lásìkò náà, gbogbo nǹkan tó ń ṣẹlẹ̀ ni òun rí.
Lẹ́yìn tó lu gbogbo wa tán, ó ní wọ́n gbé ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́ wá, òun ló sì lọ̀ ọ́ fi gbé òkú Ibrahim lọ sí ilé wọn, tó sì sọ fún wọn pé adigunjalè ni.
Ṣùgbọ́n, iléeṣẹ́ ọlọ́pàá nípìńlẹ̀ Bauchi sọ pé àwọn ti ń ṣe ìwádìí ìṣẹ̀lẹ̀ náà.
Fẹ́mi Akínṣọlá