Keyamu àti àwo̩n Asojú sòfin tutó̩ sí ara wo̩n lójú
Minisita fun ipinle ati eto ise ni orileede yii, Agbejoro agba Festus Keyamu ni awon Asoju sofin ranse si ni ilu Abuja lonii.
Won fi saarin, won si bere si ni da ibeere lorisiirisii boo lori ibi ti ise de duro lori osise egberun kan fun ijoba ibile kan.
Ijoba ibile ti o wa ni orileede yii je egberin din merindinlogbon (774). Keyamu ni ona ise naa ti jin, awon to maa gba awon eniyan egberun kan,ipinle kan ti bere ise, o ni gbogbo eto lo n lo laisi wahala kankan.
Awon asoju sofin ni ki o je ki awon ri oruko awon to n gbani sise naa. Ki awon si mo ogbon ati ete ti won n lo lati fi gba awon osise naa.
Minisita ni ki won ma se iyonu nitori akanse ise naa wa lati ile-ise Aare ni eyi ti ko tun pon dandan fun won mo lati maa dara won laamu rara nipa re.
Eyi lo fa gbonmi-sii-omi-o-too laarin won.
Igba ti oro naa n le ju ni awon asoju sofin ni ki awon wo iyewu lo pari oro naa ni eyi ti minisita yari kanle pe “ko si awo kankan lawo ewa” o ni” won o ki n te tufo aja”. Minisita ni oun ko ni ipade kankan se pelu won ti ko ba ti ni si awon oniroyin nibe.
Awuyewuye yii ni Agbejoro agba naa ba kuro ni ile-igbimo asofin won.
Yínká Àlàbí