Ẹgbẹ́ àwọn nọ́ọ̀sì kan, National Nurses United ti fẹ̀hónúhàn ní gbàgede Ilé Ìjọba America, White House, láti késí àwọn Gómìnà àti Ìjọba àpapọ̀ pé kí wọ́n ó pèsè èròjà ìdáàbòbò ara ẹni fún àwọn òṣìṣẹ́ ètò ìlera tó ń gbógun ti àrùn apinni léèmí coronaviurs.
Àwọn nọ́ọ̀sì náà sọ pe “ti ẹ ko ba daabo bo wa, a ko le daabo bo awọn alaisan wa’’.
Oríṣìríṣi àwòrán àwọn nọ́ọ̀sì àti dókítà tí Covid-19 ṣekúpa, àti àkọlé ni àwọn nọ́ọ̀sì náà gbé dání.
Ẹgbẹ̀rún lọ́nà àádọ́jọ nọ́ọ̀sì ló wà nínú ẹgbẹ́ náà, òun sì ni ẹgbẹ́ àwọn nọ́ọ̀sì tó tóbi jù l’Amẹ́ríkà
Ọmọ Oòduà Naija Gist | News From Nigeria | Entertainment gist Nigeria|Networking|News.. Visit for Nigeria breaking news , Nigerian Movies , Naija music , Jobs In Nigeria , Naija News , Nollywood, Gist and more

