Kofi 19 dẹ́yẹ sí ìpínlẹ̀ Kogi àti Cross River –Osagie
Àwámárídìí ni iṣẹ́ Elédùwà, ṣùgbọ́n ọmọ èèyàn lọ́pọ̀ ìgbà má a ń fẹ́ tú fín ìn ìdí i kóòkò láti mọ kín gán án ní ń gbénú-un rédíò fọhùn. Bí kò bá wa rí bẹ́ẹ̀, kín ló mú kí Ìjọba àpapọ̀ ó máa dábàá àti bẹ ìpínlẹ̀ Kogi àti rivers wò látàrí pé Kofi 19 ṣá fún wọn.
Mínísítà ètò ìlera ní Nàìjíríà, Dókítà Osagie Ehanire sọ pé Ìjọba yóó ṣe ìwádìí ohun tó fàá gan an tí ìpínlẹ̀ Kogi àti Cross River kò fi tíì ní àkọsílẹ̀ àrùn apinni léèmí coronavirus.
Dókítà Osagie ṣàlàyé àwọn èèyàn tí Ìjọba kọ́kọ́ rán lọ sí ìpínlẹ̀ Kogi kùnà nítorí èdè-àì-yedè tó ṣẹlẹ̀ láàrin àwọn èèyàn náà àti Ìjọba ìpínlẹ̀ Kogi.
Mínísítà ní ìgbésẹ̀ tí Ìjọba yóó gbé náà ni láti sàbẹ̀wò sí àwọn ìpínlẹ̀ padà.
Ìpínlẹ̀ mẹ́rìnlélógójì pẹ̀lú olú ìlú Nàìjíríà, Àbújá ní Kofi 19 ti wọ́ pọ̀ pẹ̀lú ohun tí a rí gbọ́ lọ́dọ̀ ọ wọn lọ́wọ́ yìí.
Dókítà Osagie ní ọ̀sẹ̀ tí ó ń bọ̀ yìí náà ni Ìjọba yóó rán àwọn sí ìpínlẹ̀ Cross River àti Kogi láti ṣiṣẹ́ ìwádìí náà.
Fẹ́mi Akínṣọlá