Ọ̀ọ̀ni lfẹ̀ wọ ilédì fún ọdún ọlọ́jọ́
Bí a bá ń ṣọ̀rọ̀ ọ̀nà, yóó sòro púpọ̀ kí á tó yọ tí ẹsẹ̀ kúrò.
Bí a bá sì ń ṣọ̀rọ̀ nípa ìṣẹ̀ṣe, òpó kan jàǹràn ni ilé Ifẹ̀ níbi tí ó ti jẹ́ pé ọdọọdún ni ọdún Ọlọ́jọ́ máa ń wáyé fún gbogbo ọmọ káàárọ̀ , o jíire paàpá àwọn ọmọ Ilé Ifẹ̀ ní ilẹ̀ Yorùbá.
Gẹ́gẹ́ bí ìṣe wọn ọ́ lọ́dọọdún, Ọba Ogunwusi ni yóó kọ́kọ́ ṣíde nípa wíwọ Ilé Oòduà kí ó tó wọ adé Aare láti jẹ́ kí ayẹyẹ náà bẹ̀rẹ̀ ní pẹrẹwu.
Lẹ́yìn náà ni ayẹyẹ tí wọ́n ń pè ní Gbajure yóó wáyé káàkiri àwọn ojuko kan ní ìlú Ifẹ̀, tí àwọn aráàlú yóó sì maa tẹ̀lé wọn káàkiri láti ṣe àjọyọ̀ náà.
Bákan náà ni Ọba Ogunwusi yóó gbàlejò àwọn tó ẹlẹ́ṣìn Ògún, Sàngó àti Ọ̀ṣun ní ààfin ọba pẹ̀lú ayẹyẹ lórísirísi.
Ní Ọjọ́ Keje tó jẹ́ kòkàárí ètò, Ọọ̀ni yóó gbàlejò ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ènìyàn láti òkèèrè àti káàkiri orílẹ̀-èdè Nàìjíríà tí wọn yóó wá láti bá wọn ṣe ayẹyẹ.
Ní ọdún tó kọjá, Ààrẹ orílẹ̀-èdè-ede Nàìjíríà, Muhammadu Buhari tó péjú sí ibi ayẹyẹ àṣekágbá náà rọ àwọn ọmọ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà àti gbogbo Adúláwọ l’ágbàáyé láti má ṣe gbàgbé ìṣẹṣe àti àṣà wọn.
Fẹ́mi Akínṣọlá