Ọmọọsẹ́ tó súnmọ́ mi jù lọ satọ́nà bí wọ́n se jí ìbejì mi gbé — Akewugbagold
Ṣé wọ́n ní olè kò ní jàgbà, kó má kó fìrí, bẹ́ẹ̀ bíkú ilé ò pani,yóó sòro díẹ̀ kí kú tòde pààyàn . Ọ̀rọ̀ kò rí bẹ́ẹ̀ ni gbajúgbajà onímọ̀ nípa ẹ̀sìn Islam, Sheikh Taofeeq Akeugbagold tú pẹrẹpẹ́rẹ̀ ọ̀rọ̀ nípa irú èèyàn tí amúgbálẹ́gbẹ̀ rẹ̀, Opeyemi Oyeleye jẹ́.
Ẹni yìí ni afurasí táwọn Ọlọ́pàá ló ṣe kòkàárí bí wọ́n ṣe jí ìbejì rẹ̀ gbé lọ.
Bẹẹ ba gbagbe, ọjọ Aje ni Ileesẹ Ọlọpaa ipinlẹ Oyo ṣe afihan oju awọn afurasi to ji ibeji Akeugbagold gbe lọ, ki wọn to ri wọn pada, ti Opeyemi si wa lara awọn afurasi naa.
, nigba to n ba sọrọ lọjọ Isegun lori iṣẹlẹ naa salaye pe, ọmọkunrin to ni laakaye ni afurasi naa, o ni ọpọlọ, to si maa n ronu kọja ọjọ ori rẹ.
“Ọmọkùnrin náà ní ẹ̀kọ́ gan-an ni, ó gbọ́n púpọ̀, èyí tó mú kí n tètè fà á mọ́ra, kódà ó ń dùn mí pé ó fẹ́ fi gbogbo ẹ̀bùn rere tí Ọlọ́run fún un ṣòfò ni, torí mo ti fi ojú ṣùn-ún pé ọjọ́ iwájú rẹ̀ yóó dára.”
Onímọ̀ nípa ẹ ẹ̀ṣìn Islam náà ní, inú òun máa ń dùn láti ṣúnmọ́ ẹni tó lóye, ìdí nìyí tí òun fi fa afurasí náà mọ́ra débi pé, òun nìkan ló máa ń wọ yàrá ìbùsùn òun, tí àwọn sì dìjọ máa ń jẹun nínú àwo kan ṣoṣo lásìkò ìsínu ààwẹ̀.
” Gbogbo bá a ṣe ń wá àwọn ìbejì mi, kò sí eléyìí tí kìí gbọ́, ìdí sì rèé tó fi nira láti tètè rí wọn mú, àdúrà mi sì ló gbà, tá a fi tètè rí wọn mú.”Akeugbagold ní àwọn èèyàn tó lọ́wọ́ nínú bí wọ́n ṣe jí ìbejì òun gbé ní àwọn nílò owó ni àwọn ṣe hùwà náà, tí àwọn sì gbọ́ pé òun lówó lọ́wọ́, òun kàn ń fi ara pamọ́ ni.
” Ọ̀kan nínú wọn ló máa ń tẹ̀lé mi lọ gba owó táwọn èèyàn bá fẹ́ sanwó Hajj tàbí owó ilẹ̀ ,torí mò ń ta ilẹ̀ àti ilé, mo tún ní oko ńlá tá a ti ń ṣe nǹkan ọ̀sìn,afurasí yìí ló máa ń bá mi gba owó, àwọn nǹkan yìí ló kó sí wọn lójú.”
Nígbà tó ń ṣàlàyé pé òun kìí fi owó jẹ àwọn òṣìṣẹ́ òun níyà, àgbà Alfa náà tún sísọ lójú rẹ pé, ẹgbẹ̀rún lọ́nà ọgọ́rùn náírà ni òun máa ń ṣan fún àwọn méjéèjì tó ń ṣe àkóso ojú òpó ìtàkùn àgbáyé òun lẹ́yìn ààwẹ̀ Ramadan.
“Mo tún máa fún wọn ní ẹgbẹ̀rún méjì
náírà ẹnì kọ̀ọ̀kan ní ojoojúmọ́, wọ́n yóó sínu ààwẹ lọdọ mi, lọ́dún tó kọjá, wọ́n gbé ìrẹsì, mílíìkì, òróró lọ sílé àmọ́ Kòrónáfairọ̀ọ̀sì kò jẹ́ kó rí bẹ́ẹ̀ lọ́dún yìí.”
Ó tun tẹ̀síwájú pé tí wáàsí ìta gbangba bá wà lásìkò ààwẹ̀ Ramadan, ọ̀kọ̀ọ̀kan
wọn yóó mú tó ẹgbẹ̀rún lọ́nà ogún náírà lọ sílé, ṣùgbọ́n ó ní Kofi-19 kò jẹ́ kí wáàsí ààwẹ̀ ṣeéṣe lọ́dún yìí, èyí tó leè mú kí owó wọ́n tó ná.
Nígbà tó ń sàlàyé bó ṣe ṣe salábàápàdè afurasí náà, tó fi dé ọ̀dọ̀ rẹ, Akeugbagold ní láti ipaṣẹ̀ èèyàn kan tó ní orúkọ rere láàrin ìlú, tó sì ń ṣe dáadáa ni òun ti mọ Ọmọdékùnnrin náà.
Ó ní òun nílò ẹni tí yóó máa ṣe àkóso ojú òpó ayélujára òun lásìkò ààwẹ̀, ní òun fi gbà á sọ́dọ̀ , láì mọ̀ pé ọmọkùnrin náà ti ṣe àìdáa rí lọdọ Ọ̀gá rẹ̀ tẹ́lẹ̀.
“Ní ọjọ́ tí wọ́n jí àwọn ìbejì mi gbé lọ, èmi pẹ̀lú rẹ la dìjọ wà nínú mọ́tò, bí wọ́n sì ṣe pè mí láti Ilé pé wọ́n ti jí àwọn ọmọ gbé lọ, a dìjọ ń lé gbogbo mọ́tò tó jọ ti àwọn ajínigbé náà ni, tó sì ń ṣe ètò lórí rédíò, bẹ́ẹ̀ ló ń bẹ̀bẹ̀ lórí ìkànnì abánidọ́rẹ̀ẹ́ rẹ̀ Facebook pé kí wọ́n tú àwọn ọmọ náà sílẹ̀.”
Akeugbagold fikún un pé afurasí náà ń fò fáyọ̀ lásìkò tí wọ́n tú àwọn ọmọ náà sílẹ̀ ni, tí kò sì sí ẹni tó fura sí i pé ejò rẹ̀ lọ́wọ́ nínú ìṣẹ̀lẹ̀ náà.
Akeugbagold ni òun ti dáríjìn àwọn afurasí ajọ́mọgbé náà, tí òun sì setán láti ràn hán lọ́wọ́ tó bá jáde ní àhámọ́, òun sì ń gbàdúrà fún pé kó yí ìwà rẹ̀ padà, kó lè di Ààfáà ńlá.
Fẹ́mi Akínṣọlá