Tinubu, má dàá sí ọ̀rọ̀ ìdìbò gómìnà Edo–PDP kìlọ̀
Ṣé látàrí a á sìnlú a à sìnlú yìí náà lọ̀rọ̀ wá di fàá ká já a báyìí, tí àwọn ẹgbẹ́ òṣèlú ń jùkò ọ̀rọ̀ lu ra wọn.
Nífèsì padà sí n tí aṣíwájú Tinubu ṣọ , ẹgbẹ́ òṣèlú “Peoples Democratic Party,PDP ” náà tí fèsì padà fún Aṣíwájú Bola Ahmed Tinubu lórí fídíò tó ti ní kí àwọn èèyàn Edo má ṣe dìbò fún Godwin Obaseki.
Gómìnà Godwin Obaseki ni olùdíje ẹgbẹ́ náà nínú ìdìbò Gómìnà tó ń bọ̀ lọ́nà.
Nínú àtẹjáde tí ẹgbẹ́ náà fi síta lójú òpó abẹ́yefò Twitter, wọ́n ní ẹ̀yìnkùlé baba Tinubu kò dé Edo, nítorí náà gàlègàlè rẹ̀ tó ń ṣe nínú fídíò ọ̀hún kò le è yí ìpinnu àwọn ará ìlú Edo padà.
Ẹgbẹ́ náà sọ pé àwọn èèyàn Edo ti pinu lọ́kàn wọn ti pẹ́ láti yan Obaseki sí ipò padà nítorí náà kí Tinubu lọ ṣa gbé jẹ́ ẹ́ mọ́wọ́.
Yàtọ̀ sí ọ̀rọ̀ ẹgbẹ́ yìí, Olùdámọ̀ràn Gómìnà Obaseki lórí ọ̀rọ̀ ìròyìn, Crusoe Osagie sọ pé kí Tinubu dá ọ̀rọ̀ rẹ̀ padà.
Ó ṣàlàyé pé àwọn èèyàn Edo kò fààyè gba baba ìsàlẹ̀ nínú òṣèlú ìpínlẹ̀ wọn nítorí náà kí Tinubu fàwọn lọ́rùn sílẹ̀.
Fẹ́mi Akínṣọlá