Àfikún owó oṣù nìkan lẹ̀rọ̀ ìyanṣẹ́lódì…NLC
Fẹ́mi Akínṣọlá
Ẹgbẹ́ òṣìṣẹ́ lorilẹede Nàìjíríà, NLC, ti sọ fún àwọn adari ẹgbẹ́ ọhun láwọn ipinlẹ pé kí wọ́n gbaradi fún ìyanṣẹ́lódì, bẹrẹ láti ọjọru, ọjọ Kẹrindinlogun oṣù Kẹwàá ọdún 2019.
Ẹgbẹ́ NLC ní òun yóò gunle iyaṣẹlodi náà tí ifọrọwerọ oun pẹlu Ìjọba àpapọ̀ kò bá so eso rere.
Nínú atẹjade kan tí ẹgbẹ́ náà fi sọwọ sí àwọn ẹka rẹ̀ ní àwọn ipinlẹ, ti akọwe àgbà ẹgbẹ́, Emmanuel Ugboaja fọwọ si, lóti sísọ lójú ọrọ náà.
Ẹgbẹ́ NLC ní, gẹ́gẹ́ bí ìwé tí òun ti kọ Ṣaájú sí àwọn ọmọ ẹgbẹ́ náà ní Nàìjíríà pe, ti ajọsọ egbẹ naa pẹlu ijọba apapọ lori afikun owo oṣu ko ba so eso rere, oun yoo bẹrẹ iyanṣẹlodi.
Ṣaájú ni ẹgbẹ awọn oṣiṣẹ ọhun ti beere afikun owo oṣu to jẹ ida mọkanla fun awọn oṣiṣẹ to wa ni ipele keje si mẹrinla, ati afikun owo oṣu ida mẹfa abọ fun awọn oṣiṣẹ ijọba to wa ni ipele karundilogun titi de ipele kẹtadinlogun.
Ni ọjọ kẹrinla oṣu karun un ọdun 2019 ni ijọba apapọ gbe igbimọ kan dide lati boju wo afikun ti ẹgbẹ oṣiṣẹ n beere fun.
Lẹ́yìn ọpọlọpọ ìpàdé àti ijiroro, ó jọ pé ẹ́gbẹ òṣìṣẹ́ àti Ìjọba àpapọ̀ kò tiì fẹnu ọrọ náà jona.
iroyinowuro