Orunmila wi Awo tan.
Ifa mi Awo ku mi Bara Agbonmiregun.
Ifa ni nibo ni Awo ku si?
Mo ni o ku awon Ajagaruwa.
Mo ni o ku awon Alsgbede orun ko mero ileke.
Mo ni o ku Okoko sii wele.
Ifa lo di obiri
Mo ni o di apawoda se
Orunmila lo di Opere
Ifa mo ni o di Ikin oloju merin.
Ani komode ma lo s’oko
Omode kekere lo s’oko
Omode kekere ba eyin Alagemo loko
Ani ki agbalagba mo lo s’odo
Agbalagba lo s’odo
Agbalagba ba iseju akan lodo
Omode kekere ko goodo he eyin alagemo
Beeni awon agbalagba ko gbodo he iseju akan lodo.
Beeni e se ti ti, ti e fi pa Oniroronjiro
Beeni e se ti ti , ti e fi pa Oniroronjiro
Beeni e se ti e fi pa Iparomonyan oju omi
Beeni e se ti e fi pa Aasemogamoga
Toun tidun yankanyankan lenu.
Bi Eleiye ba n binu
E je ka be Eleiye lowe si Eleiye.
Ki a be Ogun teere Erija
Ki a be Rjemu loropoo
Ki a be Orisa Ogiyan
Ki a bs Apakoloro ti n ba won gbere ara re dogbon Ikin.
Ki a be Ikin sakasaka
Ki a be gbogbo won lowo s’eleiye.
Aje kii roro ko je erun
Aje kii roro ko jegbin
Sebi koko puoa leewo aparo.
Bi esisi ba subu a fi ida re rori.
Bi Eleiye ba nbinu erukuku ni bee.
Ifa ki o ba mi be awon ota mi Eleiye.
Ki won ma se dina mo mi.
Ki won ma se ba temi je taya tomo.
Ki won o ma se da oro mi ru.
Ifa wa gbemi lake awon ota mi Elejye.
Tagged with: Àṣà Yorùbá