Ekaaro eyin eniyan mi, aojiire bi? Aku ise ana o Eledumare ninu aanu re yio fi ire gbogbo wa wari loni o Àse.
Ifá yi gbawa niyanju wipe ki a bo ifá pelu obi meji ati agbebo adiye, ki a si se akose ifá yi ki a fi sin gbere si orokun wa mejeeji yika, ifá ni oun koni jeki a rogun ejó o, ogun wahala koni je tiwa, ifá ni ejo yi yio fe sele laarin awa ati eniyan kan tabi egbe si egbe, ifá ni mura nibe ki a ma baa sewon tabi gbere itiju o.
Ifá naa ki bayi wípé:
“Otín ni otín ejó”
Obì ni obì ìmòràn
Emun àìrírí ni emun àràjoòjo
A difa fun kéreré ìpàpò a bu owo kan fun àgbàgbà ìpàpò lojo ti won nlo si ikunle ejó, àwon méjèjì ni won jijo nbarawon ja ti won nbarawon nsota, won ni ki kéreré ìpàpò rúbo nitori ki won baa le segun àgbàgbà ìpàpò, won ni ki àgbàgbà ìpàpò náà rúbo nitori ki won baa le segun kéreré ìpàpò, obi meji, agbebo adiye ati apolukuluku sugbon kéreré ìpàpò nikan lo rúbo ti won si sin gbéré ifá funwon, àwon àgbàgbà ìpàpò mawo niro won pesu lole won koti ogboin sebo, kee pe seni won ranse si àwon méjèjì lati ile olofin wípé ki won wa ro ejó enu won, nigbati àwon méjèjì dele olofin won duro won koju sira won, àwon kéreré ìpàpò ro ejó bee náà ni àwon àgbàgbà ìpàpò ro ejó sugbon ejó enu kéreré ìpàpò nikan ni olofin gbo, kéreré ìpàpò nikan ni won da lare won si segun àgbàgbà ìpàpò, àwon kéreré ìpàpò wa njo won nyo won nyin babalawo àwon babalawo won nyin ifá, ifá nyin Eledumare won niti won gbo riru ebo ti won rúbo ti won gbo eru atukesu ti won tu ti won si gbo ikarara ebo ni hiha ti won si ha, nje riru ebo a maa gbeni eru atukesu a maa da ladaju ko pe ko jina ifá wa bami larusegun arusegun ni a nbawo lese obarisa.
Àwon kéreré ìpàpò wa fiyere ohun bonu wípé:
Ojó ti mo bawon ru mo ro mo segun o
ojó ti mo bawon ru mo ro mo se won
Ogun ki nja ko ja kéreré ìpàpò oni ni maa ro masegun
Òrúnmìlà ni to ba se bi ise ti akápò toun ni, oni sebi adiye ki ni orókún ejó
Oni sebi oju kan ni apolukuluku njoko si njare oloko.
AKOSE IFÁ NAA: Leyin igba ti a ti fi adiye naa bo ifá tan, ao ge orokun won lotun losi ti ibi oju orokun naa yio wa laarin, ao ge ojuke ewe apolukuluku naa bee die, ao lo papo mo orokun adiye mejeji naa ti yio kunna daadaa, ao fi iyerosun teye ifá yi soju opon ao pe ifá yo si ao se adura si, ao da iyerosun naa si eleyi ti a lot yen lori ao po papo, ao fi sin gbere yika orokun wa mejeeji.
Eyin eniyan mi, mose ni iwure laaro yi wípé Eledumare koni jeki a ri ogun ejó o, ao segun gbogbo ogun toba doju kowa ako ni ri inira ninu odun yi lase Eledumare aaase.
ÀBORÚ ÀBOYÈ OOO.