Home / Art / Àṣà Oòduà / Ifá náà ki bayi wípé: Adaku Adaoku
256 odu ifa Signatures © Ifa University Photo/Moyo Okediji
256 odu ifa Signatures © Ifa University Photo/Moyo Okediji

Ifá náà ki bayi wípé: Adaku Adaoku

Ekaaro eyin eniyan mi, aojiire bi, aku ise ana o, a si tun ku imura toni, gegebi a se mo wípé oni je ojó isegun, ogun buburu yio se ninu igbesi ayé wa loni o Àse.

E jeki a fi odù ifá mimo ogundarikulola yi se iwure ti aaro yi.
Ifá náà ki bayi wípé:
Adaku
Adaoku
Ada toko nbo o daku gbonrangandan bi oko a difa fun Aikulola eyiti nse wole wode orisa, Aikulola ni koni ominira lodo orisa Eledumare, se lo ba gba oko alawo lo latari nkan ti o maa se ti yio fi di ominira, won ni seni ko lo maa ni gbogbo nkan to je èèwò orisa Eledumare ki o lo ko fun orisa, Aikulola si se béè looto, nigbati o ko àwon nkan náà de odo orisa Eledumare inu bi orisa lopolopo nitori èèwò orisa Eledumare ni àwon nkan náà, bi Orisa Eledumare se sofun àwon iranse re pe ki won di Aikulola lowo ati lese ki won gbe seyinkule ile pelu gbogbo nkan wonyen, won si di Aikulola looto won gbe seyinkule, e wo ògún tinrin moko alagada ogun to nbo lati oja ejigbomekun nibiti o tilo jagun, bi ebi se npa ni oungbe ngbe, gbogbo ara ògún lákayé lo gbe, ògún lákayé lo ni ki oun ya nile orisa ki oun ki Orisa Eledumare ki oun to maa lo sile, nigbati ògún lákayé de eyinkule orisa se lo ba Aikulola ti won de ti won si ko àwon eroja etutu re ti sibe, inu ògún dun o si bere sini jehun o je gbogbo re yo tan , bi ògún se mu ada re niyen bi o se ja okun owo ati ese Aikulola niyen o, ògún lákayé wa wole sodo orisa Eledumare o wa sofun orisa wipe oun ti da Aikulola sile orisa si gbasi lenu, bi ògún lákayé se da Aikulola sile niyen o, oun ni won se npe odù ifá yi ni “ogundarikulola sile”

Aikulola wa njo o nyo o nyin babalawo àwon babalawo nyin ifá nyin Eledumare oni riru ebo a maa gbeni eru atukesu a maa da ladaju nje ko pe ko jina ifá wa bami larusegun arusegun ni a nbawo lese obarisa.

Eyin eniyan mi, mose ni iwure laaro yi wipe ògún lákayé yio tu gbogbo wa sile ninu ide omo araye, ako ni ri ibinu ògún lákayé loni ako si ni sun ninu agbara eje o aaase.
ÀBORÚ ÀBOYÈ OOO.

English Version
Continue reading after the page break

About Lolade

Viral Video

Support Ooduarere

SUPPORT OODUARERE
Scan QR code below to Donate Bitcoin to Ooduarere
Bitcoin address:
1FN2hvx5tGG7PisyzzDoypdX37TeWa9uwb
x

Check Also

16 Ofun Meji

Ifa: The 16 Odu Ifa & Their Meaning.

The meaning of the 16 Odu Ifa of the Ifa is based on 16 symbolic or allegorical parables contained in the 16 Core Chapters or Principles that form the basis of the Ifá, a system of divination of the Yoruba people of Nigeria. The Grand Priest of Ifa, the Babalawo or Iyanifas are the Priests and Priestesses of the Ifa Oracle that receive and decode the meaning of the Divine Messages contained in the Odu Ifa Parables that are transmitted ...