Lai Mohammed fa ọmọ Nàìjíríà létí lórí ìròyìn òfegè
Fẹ́mi Akínṣọlá
Mínísítà ètò ìbáraẹnisọ̀rọ̀ àti Ìròyìn lórílẹ̀-èdè Nàìjíríà, Lai Mohammed ti ní ìjọba yóò bẹ̀rẹ̀ ṣí í ṣe àmójútó àtagbà ojú òpó ayélujára báyìí.
Ìgbésẹ̀ yìí ni láti ṣe àfọ̀mọ́ ojú òpó ayélujára kí àdínkù leè bá ayédèrú Ìròyìn àtàwọn ọrọ kòbákùngbé tó ń jẹyọ.
Lai Mohammed sọ ọ̀rọ̀ yìí níbi ìpàdé oníròyìn kan tó wáyé nílùú Abuja
Mínísítà ní èyí kò yọ àwọn oníṣẹ́ ìròyìn sílẹ̀ o. Ó ní ilé iṣẹ́ Ìròyìn tó bá ta féle fèle gan yóó fara kó o.
Àtúnṣe tí wọ́n fẹ́ bẹ̀rẹ̀ yìí yóò tàn dé ojú òpó ayélujára èyí tó sàpèjúwe pé “ó ti kọjá àtúnṣe”.
Lai Mohammed tún ní “láti ìgbà tí a ti ṣe ìfilọ́lẹ̀ ètò àyípadà yìí ni àwọn ọmọ Nàìjíríà kan ti kàn sí wa pé kí a bojú wo bí a ṣe le ṣe ìlanilọyẹ̀ lórí àwọn ayélujára náà a kò sì ní pa eléyìí tì”.
Mohammed ni kò sí ìjọba gidi kan tí yóò jókòó káwọ́ gbera kí ìròyìn òfegè sì máa fò kiri t’òun tọ̀rọ̀ àlùfàǹṣá eléyìí tó leè dáná sun orílẹ̀-èdè láì sí àyẹ̀wò kankan.
“Idi niyii ti ao fi maa koju ayederu iroyin ati ọrọ alufansa ayafi bi a ba to le gbogbo rẹ danu”. O ni tori awọn ti ṣe agbekalẹ igbimọ kan ti aarẹ Buhari fọwọ si lati kọju awọn ọrọ alufansa.