llé iṣẹ́ ọ̀lọ́pàá ,ẹ dá ìgbaniwọlé tí ẹ gùnlé dúró… Àṣẹ ilé ẹjọ́
Fẹ́mi Akínṣọlá
Ṣé àwọn àgbà ní ilé tí a fi itọ́ mọ, ìrì ni yóò wo. Ọbẹ̀ tí a fi èké pilẹ̀ ẹ rẹ̀, í í ru paná ni bẹ́ẹ̀ gẹ́lẹ́ ni ọ̀rọ̀ rí, nígbà tílé ẹjọ́ gígá nílùú Abuja pàsẹ pé kí àjọ ọlọpàá dá ètò ìgbànisísẹ́ ẹgbẹ̀run mẹ́wàá tí wọ́n ń ṣe lọ́wọ́ dúró.
Adajọ Inyang Ekwo ló fi idájọ náà janlẹ̀ pé kí wọ́n dáa dúró títí tí igbẹ́jọ́ tí àjọ ọlọpàá pe.
Èyí wáye lẹ́yin tí wọ́n so igbẹ́jó náà rọ̀. Adájọ́ àgbà Abubakar Malami wà nínú ejọ náà.
Àwọn míràn nínú ìgbẹ́jọ́ náà ni , Ọ̀gá àgbà ọlọpàá àti mínísita fún ọ̀rọ ọlọpàá.
Adájọ́ Ekwo ní gbogbo àwọn ti ọ̀rọ̀ náà kàn ní wọn gbọdọ̀ tẹ̀lé ìdájọ náà títí yóò fi pari ọ̀rọ̀ naa.
Wàhálà ejọ́ yìí bẹ̀rẹ̀ lásìkò tí àjọ ọlọpàá fẹ̀sùn kan ilé iṣẹ́ ọlọpàá pé wọ́n já ètò igbànisísẹ́ náà gbà mọ àwọn lọ́wọ́.
Àjọ ọlọ́pàá fẹ̀sùn kan ilé iṣẹ́ ọlọpàá pé wọ́n ti tọwọ́bọ ètò ìgbàniwọle náà nípa àyípada àwọn orúkọ nínú iwé orúkọ.
Tí ẹ ò bá gbàgbé ètò ìgbaniwọlé ọlọ́pàá náà bẹ̀rẹ̀ ní òpin ọdún tó kọjá.