Home / Art / Àṣà Oòduà / Odu ifa OYEKU MEJI
Oyeku meji

Odu ifa OYEKU MEJI

|| ||
|| ||
|| ||
|| ||

Ekaaro eyin eniyan mi, aojiire bi? Oni a san wa o ase.
Odu ifa to gate laaro yi ni OYEKU MEJI, ifa yi gba akapo ti odu ifa yi ba jade si niyanju wipe ki o rubo daradara nitori Ogun iku ojiji, ifa ni iku yio ye lori re.

 
Ifa naa ki bayi wipe: Ekiti bamuba ni pekun ipopo a difa fun ikuye eyiti nse omo bibi inu agbonmiregun lojo ti iku nfile re nkan firii ti arun nfile re nkan firii won ni ko karale ko rubo, obi meji, oromoadiye, obuko, eko, akara, ati aso pupa ikuye kabomora o rubo won se sise ifa fun bi iku se ye lori re niyen o wa njo o nyo o nyin awo awon awo nyin ifa, ifa nyin eledumare oni nje riru ebo a maa gbeni eru arukesu a maa da ladaju ko pe ko jina ifa wa bami laiku kangiri aiku kangiri ni a nba awo lese obarisa.

 
Ikuye wa fiyere ohun bonu wipe; nje iku ma ye lori mi o okutu ayere iku ye,
Arun ma ye lori mi o okutu ayere arun ye
Gbogbo ajogun ibi ma ye lori mi o okutu ayere iku yen.
Iku ojiji yio ye lori gbogbo wa o aaaseee.
Ti aba da ifa yi fun ikosejaye omo tuntun “IKUYE” ni ao so oruko omo naa atiwipe aso pupa ni omo naa gbudo yan laayo julo lati maa wo.
SISE ETUTU YI:………..Ao pade ninu group.
ABORU ABOYE OOO.

 

English Version:

Good morning my people, how was your night? Hope it was great, may we blessed today.
It is OYEKU MEJI corpus that revealed this morning, ifa advised whoever this corpus revealed out for to offer sacrifice so that he/she may escape sudden death.
Hear what the corpus said:
Ekiti bamuba ni peku ipopo it cast divined for ikuye the son of bara agbonmiregun when death was searching for him, sickness, calamities and all evil servants were searching for him, he was advised to offer sacrifice so that he may escape the death and all evil servants, two kola nuts, chicken, he-goat, corncake, cake beans, red cloth and he complied, aftermath he escaped death he started dancing and rejoicing praising priest the priests were praising ifa while ifa was praising God.
If perhaps this corpus came out during the ikosejaye of a new born babay, it is “IKUYE” will must name the child and his/her favorite cloth should be red cloth.
PREPARATION OF THE SACRIFICE: ……. In a group.

 

Faniyi David Osagbami

About ayangalu

Viral Video

Support Ooduarere

SUPPORT OODUARERE
Scan QR code below to Donate Bitcoin to Ooduarere
Bitcoin address:
1FN2hvx5tGG7PisyzzDoypdX37TeWa9uwb
x

Check Also

16 Ofun Meji

Ifa: The 16 Odu Ifa & Their Meaning.

The meaning of the 16 Odu Ifa of the Ifa is based on 16 symbolic or allegorical parables contained in the 16 Core Chapters or Principles that form the basis of the Ifá, a system of divination of the Yoruba people of Nigeria. The Grand Priest of Ifa, the Babalawo or Iyanifas are the Priests and Priestesses of the Ifa Oracle that receive and decode the meaning of the Divine Messages contained in the Odu Ifa Parables that are transmitted ...