Home / Art / Àṣà Oòduà / Ògún lákáayé .

Ògún lákáayé .

Ọ̀wọ́nyán rosùn porogodo lóso, Agogo ńlá ni wọ́n fi ń fọ́ri fálágbára mu, Àtàtà ńlá ni wọ́n fi ń fọ yíìrí mọrọ̀, Adífáfún Ògún tíń gbógun lọ sí Ìgbòmẹkùn-eséji, ẹbọ lawo níkóse, Ògún ló sẹbọ sètùtù lówá kóre dé ìtùtúrú

Ògún lákáayé
Oníjà oòle
Ẹjẹmu olúwọnran
Adìgìrì rebi ìjà
Koríko etídò
tíírú mìnìmìnì
Sékélé ni ń o ma rọ̀bẹ
ní pópó iyemakin
Sàgàlà lọ̀bẹ ìrè
Ọ̀bẹ ìrèmògún di ogójì
Ọ̀bẹ ìrèmògún di ọ̀wọ́ngógó
Ọmọ rọ́wọ́rọ̀wọ̀rọ́wọ́
Bí Alágbẹ̀dẹ́ kòbá rọ́wọ́
Ọmọ fínnáfìnnàfínná
bí Alágbẹ̀dẹ kòbá fínná
Tọlọ́kọ́ taládàá ni yóò mọ sùn sọ́nà oko

Ògún yeeeeeeeeeeeeeeeeeeeeeee

About Awoyemi Bamimore

VI

Viral Video

Support Ooduarere

SUPPORT OODUARERE
Scan QR code below to Donate Bitcoin to Ooduarere
Bitcoin address:
1FN2hvx5tGG7PisyzzDoypdX37TeWa9uwb
x

Check Also

Omisore

Àwàdà kẹrí-Kẹrì ni àwọn kọmití tó ní mi ò lè díje du ipò gómìnà APC ni 2026 n ṣe – Omisore

Yínká Àlàbí Awọn kọmiti to n ṣe àyẹ̀wò awọn oludije du ipo gomina labẹ ẹgbẹ́ oselu APC ti ja igbakeji gomina tẹlẹ ni ipinle Osun, Alagba Iyiola Omisore ati awọn mẹfa miiran.Wọn ni iwe wọn ko pe lati dije du ipo gomina ipinlẹ naa. Awọn mẹfẹẹfa to ku naa ni – Babatunde Oralusi, Oyedotun Babayemi, Dr. Akin Ogunbiyi, Benedict Alabi, Adegoke Rasheed Okiki, ati Senator Babajide Omoworare.Iyiola Omisore ni awada Kẹri-Kẹri ni awọn kọmiti naa n se nitori ti wọn ...