Home / Art / Àṣà Oòduà / Okiki fi Oore Ofe gbe Femi Solar jade: Fidio orin tuntun yii leku!
Femi Solar
Femi Solar King lati owo JasaMusic

Okiki fi Oore Ofe gbe Femi Solar jade: Fidio orin tuntun yii leku!

Femi omo Oladele ti gbobo eniyan mo si Femi Solar ti fi gbogbo awon ololufe re lokan bale pelu fidio orin re tuntun to pe ni GRACE nigba to n fi die ninu fidio naa to won lenu won.
Gege bi alase Sunshine Jasa Band se so, o ni kesekese ni awon eniyan ti n ri ninu ka se agbekale fidio orin to joju-n-gbese. O ni awo orin GRACE yii ni a le se apejuwe re gege bi kasakasa to je “godfather” kesekese.

“Dare Zaka lo ya fidio orin tuntun naa. Fun awon to ba si mo Dare Saka pelu awon fidio to n ti n sebo seyin, o ye ke e gba pelu mi wi pe ojumo kan ara kan lo fi n sise opolo. Ki ise eleyii tun le yato laaarin agbo amuludun agbaye, a tun se amulo awon ohun kan ti enikeni ko lo ri ninu fidio orin. Ko ni wu mi ki n so gbogbo re bayii, sebi eni a n gbe iyawo bo wa ba, won ni kii gbe ori iganna woran”, Solar fi kun alaye re bee.

 

Okiki Films ni yoo gbe fidio orin naa jade nigba to ba jina tan. Olayemi Oniroyin ni o kede re nigba to ba gori igba. Eyin ati idile yin ko si ni padanu OORE OFE nigba to ba doju iworan yin. Ase
Send Money To Nigeria Free

About admin

x

Check Also

Ọdún orò gbìnà yá, ìdájí ní àwọn olórò yóò fi máa yíde ìlú níṣẹ̀yin

Fẹ́mi Akínṣọlá Ṣe aifẹsọ kebosi,lai rẹni jo o,ati pe n ta o ba fẹ o bajẹ,o ni bi o ṣe yẹ ka ṣe e,eyi lo bi atunse abẹnu lati fopin sawuye wuye to waye latari aawọ to suyọ laarin awọn onisese ati awọn ẹlẹsin meji ti o ku(Kitẹẹni ati Musulumi).Wayi o, igbakeji alaga fun ẹgbẹ agbaagba nilu Isẹyin, Alhaji Bọlaji Kareem, ti kede pe ija ti dopin, ogun si ti tan lori aawọ ọrọ sise nilu Isẹyin.Kareem, ẹni to soju ...