Òògùn náà(Chloroquine phosphate) lè ṣiṣẹ́ fún ìtọ́jú àrùn a jà má mààlà (Coronavirus ) tó ń tàn káàkiri.
Fẹ́mi Akínṣọlá
Ọ̀rọ̀ yìí dà bí ọ̀rọ̀ ìwé mímọ́ tó sọ pé ” òkúta táwọn ọ̀mọ̀lé kọ̀ sílẹ̀, ló di pàtàkì igun Ilé.
Òògùn ibà tó wọ́pọ̀ nílẹ̀ Áfírìkà, paàpá jùlọ lórílẹ̀-èdè Nàìjíríà ní bí ogún ọdún sí ọgbọ̀n sẹ́yìn, Chloroquine phosphate ni àwọn Onímọ̀ ìṣègùn ti sọ pé, ó ṣiṣẹ́ fún ìtọ́jú àrùn Coronavirus tó ń tàn kálẹ̀ káàkiri.
Ẹ̀ka ìjọba ìmọ̀ ìjìnlẹ̀ àti ìmọ̀ ẹ̀rọ lórílẹ̀-èdè China ló sọ pé, òògùn Chloroquine ṣiṣẹ́ dáadáa lára àwọn tó ní àrùn náà táwọn ti dán -an- wò lára wọn.
Àwọn Onímọ̀ ìṣègùn òyìnbó lo Chloroquine fún ìtọ́jú ibà fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún, kí ó tó di pé òògùn náà kò ran àwọn kòkòrò tó máa ń fa àìsàn ibà mọ́.
Lójú òpó Twitter COVID-19 tí wọ́n ti ń dáwọn èèyàn lóhùn lórí àrùn coronavirus, wọ́n sọ nípa òògùn Chloroquine pé ó ń dènà àrùn coronavirus.
Ìròyìn tó tẹ wá lọ́wọ́ láti orílẹ̀-èdè China fìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé, àwọn Dókítà Onímọ̀ ìṣègùn ti dán òògùn náà wò lára àwọn tó lárùn coronavirus nílé ìwòsàn mẹ́wàá, wọ́n sì ri pé ó ṣiṣẹ́ dáadáa.
Ẹ̀wẹ̀, Onímọ̀ kan nípa òògùn òyìnbó tó bá akọ̀ròyìn sọ̀rọ̀ ṣàlàyé pé bó yá òògùn Chloroquine le ṣiṣẹ́ fún àrùn coronavirus tàbí bẹ́ẹ̀ kọ, àjọ ètò ìlera lágbàáyé(WHO) àti àjọ ilẹ̀ Amẹ́ríkà tó ń ṣàkóso oúnjẹ ló lè sọ.
Ohun tí àjọ ìlera lágbàáyé sọ ni pé ó ṣeéṣe kí òògùn àrùn coronavirus jáde ní bíi ọdún kan ààbọ̀ sí àkókò yìí.
Ní báyìí, ojú òpó Twitter tí ń yeruku lálá lórí ìròyìn pé òògùn Chloroquine dára fún ìtọ́jú àrùn coronavirus.
Ọ̀pọ̀ ló dunnú sí ìròyìn náà, bákan náà ni wọ́n ṣe ìrántí bí wọ́n ti máa ń lòògùn ọ̀hún fún ìtọ́jú àrùn ibà láti ọjọ́ tó ti pẹ́.
Harry Obi ní tiẹ̀ sọ pé, ta ló le rò òògùn Chloroquine le ṣe ìtọ́jú coronavirus, ó ní ó dájú pé, àwọn Dókítà oníṣègùn òyìnbó yóó tún ní òògùn náà nítorí wọ́n ti lo ọ̀pọ̀ rẹ̀ fún ìtọ́jú àrùn ibà tẹ́lẹ̀.
Ọ̀gbẹ́ni Adekunle ní ta ló mọ̀ bóyá òògùn Flagyl gan le ṣe ìtọ́jú àrùn HIV lẹ́yìn táwọn onímọ̀ ìṣègùn ti sọ pé, Chloroquine dára láti kojú corona virus.