Kò sí n tó burú kí abẹ òfin ba Ògbó Awo tó bá ń se bí ọ̀gbẹ̀rì .
Ilé ẹjọ́ ti dá gbajúgbajà òṣèré sinimá, Fúnkẹ́ Akíndélé àti ọkọ rẹ̀ Abdulrasheed Bello lẹ́jọ́ pé ó jẹ̀bi ẹ̀sùn tí wọ́n fi kàn án pé ó lòdì sí òfin kónílégbélé tí ìjọba Ìpínlẹ̀ Èkó gbé kalẹ̀ lórí dídẹ́kun àjàkálẹ̀ àrùn Coronavirus nípìńlẹ̀ Èkó àti orílẹ̀-èdè Nàìjíríà.
Ilé ẹjọ́ rán àwọn méjéèjì lọ sí iṣẹ́ ìsìnlú fún wákàtí mẹ́ta lóòjọ́ fún ọjọ́ mẹ́rìnlà, yàtọ sí ọjọ́ Sátidé àti Àìkú.
Bákan náà ni iléẹjọ́ ní kí wọ́n san owó ìtanràn ẹgbẹ̀rún lọ́nà ọgọ́rùn náírà.
Bákan náà ni ìdájọ́ ọ̀hún tún ní kí ọ̀kọ̀ọ̀kan lọ́kọláyà náà yóó lọ sí ibùdó pàtàkì mẹ́wàá ní ìpínlẹ̀ Èkó láti ṣe ìdánilẹ́kọ́ọ̀ àti ìlanilọ́yẹ lórí ìjìyà tó wà fún ẹni tó bá ṣoríkunkun sí òfin kónílé ó gbélé.
Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n gbọdọ̀ fi orúkọ àti nọńbà ìbánisọ̀rọ̀ gbogbo àwọn tó kópa níbi àjọyọ̀ náà.
Bákan náà nìròyìn míì ti fìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé, Azeez Fashola tí ọ̀pọ̀ èèyàn mọ̀ sí Naira Marley tí àwọn agbófinró tí kọ́kọ́ kéde ṣaájú pé àwọn ń wá ló tí fúnra rẹ farahàn báyìí ní àgọ́ Ọlọ́pàá.
Ìròyìn ń bọ lórí rẹ̀ láìpẹ́ ẹ fojú sọ́nà
Òòlù ìdájọ́ ré bá Fúnkẹ́ Akíndélé àti ọkọ rẹ̀ lẹ́yìn, owó ìtánràn, ìgbélé tipátipá, iṣẹ́ ìsìnlú bíi bọ̀kílẹ̀ àfojúdi .
Fẹ́mi Akínṣọlá