Vietnamni , ẹ wá dá oko ìrẹsì sílẹ̀ ní Nàíjíríà, dípò kíkórẹsì wọlé– Oshiomole fèsì ẹ̀bẹ̀
Fẹ́mi Akínṣọlá
Bí Ìjọba Nàíjíríà se gbé àwọn ẹnu ọ̀nà àbáwọlé sí orílẹ̀ -èdè yìí tìpa ti ń mú kí orí ta àwọn lórílẹ̀-èdè tó múlé tì wá àti àwọn tó wà nílẹ̀ òkèèrè.
Kódà, ìsòro yìí pọ̀ tó bẹẹ fún orílẹ̀-èdè Vietnam tó fi gbé aṣojú dìde pé kó wá rawọ́ ẹ̀bẹ̀ síjọba Nàíjíríà láti sí ẹnu ibodè rẹ̀ padà, kí òun leè kó ìrẹsì òun wọlé- lọ́pọ̀ yanturu.
Igbákejì Olóòtú Ìjọba Vietnam, Vuong Dinh Hue tó kó àwọn aṣojú náà wá sí Nàíjíríà ti wá ń rawọ́ ẹ̀bẹ̀ sí ẹgbẹ́ òsèlú APC tó ń tukọ Ìjọba Nàíjíríà lọ́wọ́ láti báwọn bẹ Ààrẹ Muhammadu Buhari, kí ẹnu bodè wa leè di sísí padà.
Ìlú Abuja ni ìgbákejì Olóòtú Ìjọba Vietnam náà ti rawọ́ ẹ̀bẹ̀ yìí lásìkò tó sàbẹ̀wò si Alága ẹgbẹ́ òsèlú APC nílẹ̀ wa, Adams Oshiomole lọ́fíìsì rẹ̀, tó sì tún kéde pé nítorí bí ọrọ náà se ká àwọn lára tó, àwọn yóò tún lọ
dírẹ̀ẹ́bẹ̀ níwájú igbákejì Ààrẹ, Yẹmi Ọsinbajo lórí rẹ̀ pẹ̀lú.
Nígbà tó ń kí àwọn àlejò rẹ̀ kaabọ sílẹ̀ yìí, tó sì ń fèsì lórí ìbéèrè wọn, Adams Oshiomole ní àrè kò sèlú, kí wọ́n má fìse hàn wá ní Nàíjíríà nítorí báyìí ni n ó se nǹkan mi kò leè yípadà,bÍ ohun gbogbo tilẹ̀ padà.
Oshiomole ni lórílẹ̀-èdè Nàíjíríà kò leè dáhùn sí ẹ̀bẹ̀ wọn láti sí ẹnu bodè wa, tó sì rọ àwọn aṣojú ilẹ̀ Vietnam pé kí wọ́n wá gba ilẹ̀ sorilẹede Nàíjíríà láti dá oko ìrẹsi ni yóò pé wọn.
Ó ní ọmọjá ti kúò niye tí wọ́n ń rà á, nítorí Nàíjíríà kò ní jẹ́ ààtàn èròjà tó ti bàjẹ́ mọ́ fún àwọn orílẹ̀-èdè kan, tí wọ́n fẹ́ràn à tí máa da èròjà olóró asekúpani wọn sí .
Alága ẹgbẹ́ APC fikún un pé digbí ni àgádágodo yóò wà láwọn ẹnu bodè e wa títí táwọn orílẹ̀-èdè tó múlé tì wá yóò fi bọ̀wọ̀ fún òfin to de ìbáṣepọ̀ okoòwò láàrin orílẹ̀-èdè kan sí èkejì.