Ilé-ẹjọ́ fi mílíọ̀nù mẹ́wàá náírà fa APC létí
Ejo ti ile-ejo giga to fi ikale si ilu Abuja da ni ojo ketala, osu yii ni egbe oselu APC ni awon ko fara mo. Eyi ko tii saba waye ri ni orileede yii, ki ile-ejo giga da ejo ki awon kan wa ni won ni lati tun se ayewo re.
Ejo naa lo fagi le ibo to gbe David Lyon wole gege bi gomina ipinle Bayelsa labe egbe oselu APC. Awon egbe PDP ni won pejo pe iwe eri igbakeji gomina naa ko moyan lori rara. Won ni orisiirisii oruko lo wa lori iwe eri igbakeji gomina naa, iyen Seneto Biobarakuma Degi-Eremienyo.
Ile ejo ni ki awon to ni ejo ko te awon lorun fa asise awon jade sugbon ko si agbejoro to le fa asise Kankan jade ninu ejo naa.
Eyi mu ki ile-ejo giga naa fi milionu mewaa naira fa egbe APC leti. Ile-ejo ni ki won ma se je ki iru re waye mo.
Láti ọwọ́ Yínká Àlàbí