Wọ́n gbẹ̀mí olórí ẹgbẹ́ jàǹdùkú ”One Million Boys” n’Ìbàdàn
Ọmọ ò fìgbàkan láyọ̀lé, ẹni ọmọ dúró sin onítọ̀ùn ló bímọ.
Gbogbo ẹni tó bá bí jàǹdùkú, olè, gbàjùẹ, kọ̀lọ̀rànsí l’ọ́mọ, kónítọ̀ùn ó má tíì yọ̀ láyọ̀jù nítorí pé *ÀBÍKÚ ÀGBÀ* ló bí.
Ó díá fún bí wọ́n ṣe ṣekúpa olórí ”Onẹ Million Boys”, Biola Ebila.
Iléeṣẹ́ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ ló fìdí ọ̀rọ̀ náà múlẹ̀ fún akọròyìn nírọ̀lẹ́ ọjọ́ Àìkú.
Lágbègbè Olómi nílùú Ìbàdàn ni a gbọ́ pé ọwọ́ pálábá ẹ̀rùjẹ̀jẹ̀ olórí ikọ̀ oní mílíọ̀nù kan ọkùnrin ”One Million boys” Ebila ti ṣégi níbi tí ó ti dágbére fáyé.
Iléeṣẹ́ ọlọ́pàá sọ pé òhun yó fi ẹ̀kún rẹ́rẹ́ bí Ebila ti dèrò ọ̀run síta láìpẹ́.
Láti inú oṣù karùn ún ni iléeṣẹ́ ọlọ́pàá ti sọ pé àwọn ń wá Ebila lẹ́yìn tí wọ́n fẹ̀sùn kàn án pé ó lọ́wọ́ nínú ìṣekúpani olórí ẹgbẹ́ òkuǹkùn míì, Ekugbemi.
Bí ìtẹ̀síwájú ìròyìn yìí láti ilé iṣẹ́ ọlọ́pàá bá tí ń lọ, a o níí jẹ́ kétí yín ó di síi.
Fẹ́mi Akínṣọlá