Home / Art / Àṣà Oòduà / Igbeyawo Asofin Moji Lawal niluu Eko leku!

Igbeyawo Asofin Moji Lawal niluu Eko leku!

Arabirin Moji Lawal, okan ninu awon omo ile igbimo asofin ipinle Eko segbeyawo alarinrin lopin ose to koja yii pelu oko re, John Paul to je onisowo pataki.

Arabirin Moji, eni to je obirin akoko ti o ma soju ekun Apapa nile igbimo asofin ipinle Eko naa lo je omidan kan soso laaarin awon asofinbirin saaju ko to so yigi pelu oko re lose to koja yii.

Arabirin Moji, eni to ti figba kan sise pelu gomina Ipinle Eko nigba kan ri, Bola Tinubu, gege bi oludamoran fun awon iroyin to ni i se pelu imo ero, lo lodije ninu eto idibo abele egbe APC pelu awon oludije bi ogorun ko to di wi pe o jawe olubori lati kopa ninu eto idibo gbogboogbo.

Ninu eto idibo gbogboogbo naa lo tun ti pegede lati je okan lara awon omo ile igbimo asofin Ipinle naa.

Eto igbeyawo ti won se ni ilana esin musulumi naa la gbo wi pe o waye leyin ti toko-toya naa ti lo si kootu lati lo so yigi won labe ofin.

Oniroyin: Olayemi Olatilewa

About admin

Viral Video

Support Ooduarere

SUPPORT OODUARERE
Scan QR code below to Donate Bitcoin to Ooduarere
Bitcoin address:
1FN2hvx5tGG7PisyzzDoypdX37TeWa9uwb
x

Check Also

Free Dele Farotimi | Seun Kuti