Home / Art / Àṣà Oòduà / Odu ifa IWORI MEJI
IWORI MEJI

Odu ifa IWORI MEJI

| | | |
 |    |
 |    |
| | | |

 Ekaaro eyin eniyan mi, aojiire bi? Aku isimi opin ose, emin wa yio se pupo re laye ase.
Odu ifa IWORI MEJI lo gate laaro yi, ifa yi gba akapo ti o ba jade si niyanju wipe ki o se etutu daradara latari omo to maa bi ki awon omo naa ma baa ya papanlagi ogara olosa omo, ifa yi si gba alaboyun to nbe nisakani wa niyanju tabi to ba je wipe alaboyun ni a difa yi fun, ifa ni ki o fi aso to nbe lara re lasiko ti won da ifa yi fun rubo nitori ki o ma baa fi omo inu re bi ogara olosa lomo o.

 
Ifa naa ki bayi wipe: Ogun lo ja bi iji wolu orisa oko lo rin ihoho woja a difa fun Yewande eyiti yio loyun olosa sinu won ni ko karale ebo ni ki o wa se, (obi meji,iyoku wa ninu group mi.ati igba ewe ayajo) ifa sugbon o koti ogbon sebo o mawo niro o pesu lole o worun yanyanyan bi eniti koni ku o pawon iya lamunita muni rahunje nigbati Yewande maa bimo omo se okunrin gbalaja omo si ndagba bi eni a nro omo si di ogbologbo ogara olosa ponbele o bere sini nwu iwa ibaje kiri o nba oruko Iya re je kaakiri agbegbe, bi oruko Yewande se baje niyen o to si di eni yepere lawujo awon eniyan o wa bere sini nyin babalawo re lodi nje riru ebo ni gbeni airu ki ma ngbeniyan ko pe ko jina eyi kori ifa johun biti nse biila more.

 
Awon eniyan wa fiyere ohun bonu wipe: Yewande iwo ni o o seni o
Yewande iwo ni o o seniyan
Iwo loo loyun to fi bi ole lomo
Yewande iwo ni o o seniyan
Eyin eniyan mi, mo gbaladura laaro yi wipe ako ni bawon bi ole lomo, omo wa koni darapo mo awon ogara olosa, ako ni bimo to maa ba oruko wa je to si maa sowa di eniyan yepere laarin ilu o aaaseee.

 

English Version:

Continue After The Page Break To Read English Version

About ayangalu

VI

Viral Video

Support Ooduarere

SUPPORT OODUARERE
Scan QR code below to Donate Bitcoin to Ooduarere
Bitcoin address:
1FN2hvx5tGG7PisyzzDoypdX37TeWa9uwb
x

Check Also

Aya but not Iyawo is the original Yoruba word for wife.

Did you know that AYA, not IYAWO, is the Yoruba language’s original word for wife? These days, the latter is utilized more frequently than the former. I’ll explain how Iyawo came to be. Wura, the first child and daughter of the King of Iwo (a town in Yoruba), was in the process of picking a bride and had to decide which one would be best for her.Like Sango, Ogun, and other well-known male Orisa, Yoruba Orisa traveled to Iwo to ...