Home / Art / Àṣà Oòduà / Ifa naa ki bayi wipe…
Babalawo Ifakayode Ajani

Ifa naa ki bayi wipe…

Ekaaro eyin eniyan mi, aojiire bi? Aku ise ana o, a sin ku isimi opin ose, eledumare yio saanu wa o ao ri tiwa se loni, iyan jija koni ranwa lo sibiti ako fe o ase.
Odu ifa ogbeweyin ni a maa fi se idanileko toni, ifa ni ki a sora fun iyan jija, nkan ti ao ba mo ifa ni ka mase sope eni to nsoro nipa re nparo o, ifa loun koni jeki a gbere itiju latari iyan jija o ase.

 
Ifa naa ki bayi wipe:
orunmila lo di majaro(argue with a lie) Ifa moni ko majaro mi emi ni mo ja jaaja ti mo japa aja emi ni mo jaaja ti mo ja funfun lele adaba(dove) aseta nrele ado erimin nrode owo orunmila loun nroke ijeti nile baba oun, orunmila loun ma ri nkan o awon eniyan won ni kini oun tori? orunmila dahun wipe oun ri eni to kole ti kii ngbe inu re to je wipe ita re lo ngbe, gbogbo eniyan paruwo haaaa! won ni iro ni pe bawo ni eniyan yio se kole ti ko ni gbe inu re to je wipe ita re ni yio maa gbe, orunmila ni ki won tele oun kalo orunmila ba muwon de ibiti agbon (that powerful insect that use to build house on celling or up a tree) kole si orunmila wa beere wipe talo ko ile yi?

 

won ni agbon ni orunmila ni ibo lo ngbe ninu ile re? won da orunmila loun wipe ita re ni orunmila wa sope eniti o kole ti kii ngbe inu re to je wipe ita re lo ngbe niyen, gbogbo won paruwo heeeeee! won looto ni, orunmila tun lo di majaro mi emi ni ki o mase jaro mi oni emi ni mo ja jaaja ti mo japa aja emi ni mo ja jaaja ti mo ja funfun lele adaba aseta nrele ado erimin nrode owo orunmila loun nroke ijeti ile baba oun, orunmila loun ma tun ri nkan won ni kini baba tun ri ? won ni o bere iro niyen o! orunmila loun ri alenu male soro kan ni won ni nibo lo ti ri?

 

orunmila ni ki won bo omobinrin kan si ihoho won wa bo omobinrin naa si ihoho nigbati won bo tan ni orunmila wa fowo sibi abe(private part) re oni kilo jo? won dahun wipe o jo enu orunmila ni se o nsoro? won ni rara ko ki nsoro Orunmila ni nkan to lenu ti ko le soro niyen won tun paruwo heeeee ! wipe otito ni o, orunmila loun ma tu ri nkan o, won ni ki baba mari nkankan mo pe iro nla loku to fepa, orunmila wa dahun wipe oun ri oku aja(dead dog) to jeko(corn palp) ju aaye aja lo, won ni se Won o so bee pe iro ni baba yi fe pa won ni bawo ni oku aja se fe je eko ju aaye aja lo?

 

orunmila ni ki won mu aja kan wa won mu aja Jade oni ki won bo eko fun won bo eko kinni fun o je won bo ikeji fun o je won bo iketa fun ko le je de idaji nigba to ti yo, orunmila wa sope ki won lupa won ba pa aja oni ki loda yi? won ni oku oni ki won lo se pelu efinrin, ata, alubasa, epo ati iyo won wa se nigba ti won se tan oni ki won ko apere eko meta wa (three basket of corn palp ) won ko Jade won bere si nfi aja yen njeko titi ti eko fi tan won tun ni kan ko apere meta miran wa won tun fi je aja titi to fi tan, orunmila wa beere wipe kini won fi je apere eko mefa?

 

won wa dahun wipe oku aja ni orunmila wa sope nje oun ko so fun yin pe oku aja le jeko ju aaye lo won tun paruwo won ni otito ni, orunmila tun lo di majaro moni IFA ki o mase jaro mi emi ni mo ja jaaja ti mo japa aja emi ni mo ja jaaja ti mo ja funfun lele adaba aseta nrele ado erimin nrode owo orunmila loun nroke ijeti ile baba oun, orunmila loun maa tun ri nkan o won ni ki orunmila mase tun ri nkankan mo won ni o ti nso otito lati aaro ki o ma baa fi abuku gbeyin, orunmila ni oun ri oku ewure to fohun ju aaye lo gbogbo eniyan paruwo haaa! won ni baba yi wa nparo wayio won ni bawo ni oku ewure se maa fohun ju aaye ewure lo baba akeyo?

 

orunmila ni ki won mu ewure nla kan wa won mu ewure jade orunmila ni ki won maa lu legba(stroke of cane) won wa be re si lu legba ewure wa nke sugbon bo se keto won ko gbohun re nile karun, orunmila wa ni ki won lupa won wa pa oni ki won bo awo re (to remove the skin) won wa bo awo re oni ki won se ewure yen, ki won gun iyan ki won ro oka, igba yen ni won gbeju igi meji won fi awo naa bo loju won fi tagiri hu irun ara re orunmila wa beere wipe kini eyi eleyi?

 

won dahun wipe ilu (drum) won gbesa sinu oorun(they placed it in the sun) nigbati eran ati ounje jina gbogbo won wa bere sini jehun won jehun yotan orunmila niki won gbe ilu wa won bere si nlu ilu gbogbo won wa njo won nyo, awon eniyan to wa ni abule(,village) moorin won ngbo bi ohun ilu se ndun kikankikan ni awon naa ba wa won jojojo orunmila wa ni ki won dawo ilu duro won wa duro orunmila bere lowo awon ti won wa lati abule moorin pe bawo ni abule won se jina to? won wa dahun wipe abule Karun ni oun ti ngbo ilu, orunmila wa ni se oun ko sofun yin wipe oku ewure fohun ju aaye lo, gbogbo won ho yeeeee! won ni otito ni o, won ni gbogbo oro ti orunmila bati nso lati oni lo won koni ja niyan mo laelae.

 

Iwo olugbo mi ifa yi kilo fun e wipe ki a mase maa jiyan nipa nkan ti ako mo ki iyanjija ma baa maa le oloore jina siwa. Idi niyi to fi je wipe oku ewure ni a fi nbo ifa ogbeweyin nitori ki omo araye ma baa pohun mo wa lenu, ao bo awo ewure naa ni ako gbudo sun nina ao fi se ilu. Mo gbaladura wipe aye koni pohun mowa lenu, ifa yi ki nlo sibi ti won ti nsin oku tutu, ki nlo si Ibadan tabi fe omo Ibadan ni oko/ iyawo, ifa yi ko gbudo fibi San fun oloore, ifa yi ki nta ayo olopon, ki a sin rubo nitori aisan gidigidi.Gbogbo wa koni fi aisan lo gba o Aseee. ABORU ABOYE OOO.

 

 

English Version

Good morning my people, how was your night?

Hope it was greatly enjoyed, happy weekend to you all, i pray that God will see us through today amen.
my today’s sermon comes from the ogbeweyin corpus which says we must not argue about what we don’t know so that we may see a benefactors in life also we may not end up in jail because of this argument.
Hear what the corpus said:
orumila said Don’t argue with my word i said ifa don’t argue with my words, am the one that arguing to the extent that i tear off dog’s hand am the one that arguing to the extent that i tear off the white feather of dove aseta is going to ado town, erimin is going to owo town orunmila said he is going to ijeti hill his father’s house, orunmila said he saw a strange thing and peoples said what did he saw? he said, he saw somebody that built house but not living inside it rather it lives outside, the crowd shouted ahhh! that is a lie, that how could somebody built house and not leaving inside it but live outside orunmila told them to follow him, when they reached where one dangerous insect like bee called”agbon” built its house, orunmila said where did this insect is living? they all said outside orunmila said that is the person that built house but not living inside it but living outside, all of them shouted yesss! that is true. he said again that he saw something, but peoples were messed him that he wanted to lie this time around becase he has got the first one, they asked him that what again?

 

he said he saw somebody that have mouth but she couldn’t talk, but peoples refused to believe him he pointed out a lady and he ordered someone to naked her and they did, he pointed the private part of that lady that what does it resemble? people said mouth orunmila said did it talk? they all said no! he said that is somebody that have mouth but never talk, peoples shouted yesss! orunmila is truly genius indeed. when it is a while orunmila also said he saw another strange thing, they all responded that he should go ahead, orunmila said he saw a dead dog eating corn palp or corncake more than live dog but people shouted and said lie!!! that how is it possible for a dead dog to eat corn palp than live one?
Orunmila said they should bring out one dog and they did so, he gave this dog one palp the dog ate it up two corncake but when he gave the third one to the dog, the cannot ate it to the half before it couldn’t eat it anymore, orunmila said they should killed the dog and make it soup and they did so, orunmila ordered for three basket of corncake they started using that dead dog meat to eating it till they finished it, and he also ordered for another three baskets they also finished it with that dog’s meat orunmila now asked that what did they used to ate all that six baskets of corncake?

 

they said the meat of dead dog, orunmila said, didn’t i told you that a dead dog can eat more than the live one, they all said yesss! it is true. Orunmila said don’t argue with my word i said ifa don’t arguing with me, am the one arguing to the extent that i tear off dog’s hand am the one arguing and tear off a white feather of a dove, the aseta is going to ado town the erimin is going to owo town orunmila said he is going to ijeti hill his father’s house, he said he saw another thing but people were saying that he shouldn’t put himself to a shame because he has been telling them the truth since so he should not tell a lie that will destroy his good deed, orunmila said he saw a dead goat that speak aloud than a live one, but everybody said is a great lie, he said they should bring out a goat and they did so he started flogging it but the goat voice didn’t reach the next five house, orunmila told them to killed it and remove its skin and cook the rest with soup ingredient and also differences type of foods should prepare and they did so, orunmila made that skin a drum when they ate all the foods he started druming and they were dancing to the extent that peoples in about one kilometer heard the sound of the drum and they came to see what is happening, orunmila now said didn’t he told you that a dead goat is loudable than live goat they all said yess!!! that is true ooo, and they all promised that they will never arguing with orunmila’s word till the end of the world.

 
My people, I pray today that too known will not be our portion, argument will never send us to jail and it will not distracted us from our benefactors amen.

 

Faniyi David Osagbami

About ayangalu

Viral Video

Support Ooduarere

SUPPORT OODUARERE
Scan QR code below to Donate Bitcoin to Ooduarere
Bitcoin address:
1FN2hvx5tGG7PisyzzDoypdX37TeWa9uwb
x

Check Also

16 Ofun Meji

Ifa: The 16 Odu Ifa & Their Meaning.

The meaning of the 16 Odu Ifa of the Ifa is based on 16 symbolic or allegorical parables contained in the 16 Core Chapters or Principles that form the basis of the Ifá, a system of divination of the Yoruba people of Nigeria. The Grand Priest of Ifa, the Babalawo or Iyanifas are the Priests and Priestesses of the Ifa Oracle that receive and decode the meaning of the Divine Messages contained in the Odu Ifa Parables that are transmitted ...