Ẹ wọ ìbòmú tàbí kí ẹ rugi oyin – Iléeṣẹ́ ọlọ́pàá
Ọlọ́pàá èwo n tèpè ni àṣà tó gbayé kan tẹ́lẹ̀ , ṣùgbọ́n ní àsìkò kòró yìí, ó dà bí ẹni pé wọ́n ti sún ilé iṣẹ́ ọ̀hún kan ògiri báyìí bí ó tí n ṣọ̀rọ̀ lókè ohùn látẹnu Kọmíṣọ́nnà ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Ògùn pẹ̀lú kìlọ̀ pé ẹnikẹ́ni tí kò bá wọ ìbòmú yóó dèrò àgọ́ wọn.
Iléeṣẹ́ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ náà ní ó yani lẹ́nu pé ọ̀pọ̀ olùgbé ìpínlẹ̀ ọ̀hún ni kò kọbi ara sí wíwọ ìbòmú lásìkò tí wọ́n bá jáde sí ìgboro.
Nínú àtẹjáde tí alukoro ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Ògùn, Abimbola Oyeyemi fi léde, ó ní púpọ̀ àwọn awakọ̀ ló má a ń kó èrò tó pọ̀ ju ìlànà tí ìjọba gbé kalẹ̀ nípa títakété síra ẹni.
Kọmíṣọ́nnà ọ̀hún wá rọ àwọn olùgbé ìpínlẹ̀ náà láti tẹ̀lé gbogbo Ìlànà tí àwọn elétò ìlera gbé kalẹ̀, papà á jùlọ lílo ìbòmù, bí bẹ́ẹ̀ kọ́, ẹnikẹ́ni tí ọwọ́ bá tẹ̀ yóó rugi oyin.
Fẹ́mi Akínṣọlá