Gómìnà ìpínlẹ̀ Abia, Okezie Ikpeazu ti fara kásá àrùn Covid-19
Bí àwọn èèyàn kan ṣe rò pé eré orí ìtàgé ni ariwo t’íjọba ń pa lórí àjàkálẹ̀ àrùn apinni léèmí Kòrónáfairọ̀ọ̀sì yìí, bẹ́ẹ̀ ni Ìjọba lẹ́lẹ́kaǹka náà n ké tòòò lórí pé ẹ má fàìmọ̀kan gbẹ̀mí ara a yín. Ẹ má kú síìjọba lọ́rùn.
Àrùn apinni léèmí Kofi -19 yìí kò mojú ẹnikẹ́ni o. Àfihàn rẹ̀ pé kò dá ẹnìkan sí ni ti Ìjọba ìpínlẹ̀ Abia tí Gómìnà wọn níbẹ̀, Okezie Ikpeazu,tó sẹ̀ṣẹ̀ lùgbàdi àrùn apinni léèmí ọ̀hún Kòrónáfairọ̀ọ̀sì .
Gómìnà ọ̀hún ni Gómìnà kẹrin tí yóó fara káásá àrùn náà láti ìgbà tí àrùn náà ti wọ orílẹ̀-èdè-ede Nàìjíríà lósù kejì ọdún tí a wà yìí. 2020.
Agbẹnuṣo Gómìnà ọ̀hún, Onyebuchi Ememanka tó fìdí Ìròyìn náà múlẹ̀ fákọ̀ròyìn sọ pé Gómìnà ọ̀hún ti wà ní ìgbélé, àti pé àwọn akọ́sẹ́mọsẹ́ dókítà ti ń ṣe ìtọ́jú rẹ̀.
Ememanka ní kí àwọn èèyàn ìpínlẹ̀ náà má fòyà, nítorí Gómìnà náà kìí ṣe Gómìnà àkọ́kọ́ tí yóó lùgbàdi àrùn ajániláyà pàtì náà ní Nàìjíríà.
Ṣaájú ni Kọmíṣọ́nnà ọrọ̀ tó ń lọ ní ìpínlẹ̀ ọ̀hún, John Okiyi Kalu ti kọ sọ nínú àtẹ̀jáde kan pé Gómìnà náà ti fún ìgbákejì rẹ̀ ní àṣẹ láti delé dè é kí èsì àyẹ̀wò àrùn náà tó jáde.
Ọgbọ̀njọ́, oṣù karùn ún ọdún 2020 ni Gómìnà ọ̀hún gbà láti ṣe àyẹ̀wò, tó sì pàṣẹ pé kí gbogbo àwọn tó ń bá òun ṣe ṣèjọba ṣe bẹ́ẹ̀.
Ọjọ́ kejì oṣù Kẹfà ni èsì àyẹ̀wò náà jáde ṣùgbọ́n, kò ní àrùn ọ̀hún.
Ní ọjọ́ Kẹrin kan náà ni ó tún àyẹ̀wò náà ṣe tí èsì sì fihàn pé ó ti gbàlejò àrùn apinni léèmí kòrónáfairọ̀ọ̀sì yìí.
Fẹ́mi Akínṣọlá