Home / Art / Àṣà Oòduà / E̩ Fi Àdúrà Rànmí Lọ́wọ́, Nítorí Ọmọkùnrin Mi Ti Lùgbàdi Àrùn Coronavirus … Igbákejì Ààrẹ Orílẹ̀ Yìí Nígbà Kan
Atiku

E̩ Fi Àdúrà Rànmí Lọ́wọ́, Nítorí Ọmọkùnrin Mi Ti Lùgbàdi Àrùn Coronavirus … Igbákejì Ààrẹ Orílẹ̀ Yìí Nígbà Kan

Ẹ fi àdúrà rànmí lọ́wọ́, nítorí ọmọkùnrin mi ti lùgbàdi àrùn coronavirus … igbákejì Ààrẹ Orílẹ̀ yìí nígbà kan

Fẹ́mi Akínṣọlá

Àjàkálẹ̀ àrùn kan tí gbogbo àgbáláayé ń kó bẹ́ẹ́rẹ́ fún lásìkò yìí tí kò mojú Ọba tìjòyè mẹ̀kúnù àti olówó ló tí kọlu ọmọ ìgbákejì Ààrẹ Orílẹ̀ yìí tẹlẹ o .
Olùdíje fún ipò Ààrẹ fẹ́gbẹ́ òṣèlú PDP, Atiku Abuabakar ló fọ̀rọ̀ yìí léde lójú òpó Twitter rẹ̀ lálẹ́ ọjọ́ Àìkú.

Atiku ṣàlàyé pé òun ti sọ fún àjọ tó ń gbógun ti àjàkálẹ̀ àrùn ní Nàìjíríà, NCDC, àti pé ọmọ náà ti ń gba ìtọ́jú nílé ìwòsàn olùkọ́ni Fásitì Abuja tó wà ní Gwagwalada.

”Inú mi yóó dùn tí ẹ bá le fi ọmọ mi sínú àdúrà yín, kí oníkálùkù rọra máa ṣe nítorí òtítọ́ ni pé àrùn coronavirus wà níta,” Atiku ló sọ bẹ́ẹ̀.

Atiku tún gbóríyìn fáwọn òṣìṣẹ́ ilé ìwòsàn káàkiri orílẹ̀-èdè Nàìjíríà fún iṣẹ́ takuntakun tí wọ́n ń ṣe lásìkò àjàkálẹ̀ àrùn covid-19 yìí.

”Mo rọ gbogbo ọmọ Nàìjíríà pé kí wọ́n má mi kàn tí a ó fi ṣẹ́gun àrùn coronavirus ní Nàìjíríà,” Atiku ló wòye bẹ́ẹ̀.

Ọgbọ̀n èèyàn làjọ NCDC ti kéde pé wọ́n tí ní àrùn afopin sí mímí èémí tí wọ́n ń pé ní coronavirus ní orílẹ̀ yìí, nínú èyí tí àwọn méjì ti rí ìwòsàn.

Send Money To Nigeria Free

About ayangalu

One comment

x

Check Also

Bashir El-rufai: Atiku Paid For A Waiver To Travel to USA #CorruptionOnSteroids #EmpireOfCorruption

He gets a waiver each time. He has corruption cases in U.S courts. But as usual money can buy access even in saner climes such as the U.S, Sarki na. Welcome to the #EmpireOfCorruption