Home / Art / Àṣà Oòduà / Ifá naa ki bayi wípé…

Ifá naa ki bayi wípé…

Ifá gba gbogbo akápò re niyanju wípé ki won o rubo nitori ki a baa le ri orí ayé wa, ki a baa le de ile ileri, ifá ni nkan yio soro tabi le die fun awon ti won ba koti ogboin sebo, ifá ni atirise tabi ri ona lo yio fe soro funwon, ifá ni ki a rubo nibe, ifá ni tiwa koni soro se, ifá ni ao ri ona lo laye.


Ifá ni ki a bo ògún lákayé, ifá ni ògún lákayé yio lana funwa o, obi meji, ako aja, agbata emun, epo ati iyo, ti a ba si ti bo ògún lákayé yi tan ki a gbe orí aja naa le lori.
Ifá si tun sope ki a rubo, ki a ni aporipo/karahun orí ewure ati sakiti aro, ki a fi rubo nibe nitori ki a baa le gun oke olà.

Ifá naa ki bayi wípé:
Òrúnmìlà lo di àjàwárí
Moní o di àjàwárí
Òrúnmìlà ní bi ògún lákayé ba pa igba aja, orí re ni yio maa jàwá

Òrúnmìlà lo di àjàwárí
Moní o di àjàwárí
Òrúnmìlà ní bi Ìja ba pa igba akuko, orí re ni yio maa jàwá

Òrúnmìlà lo di àjàwárí
Moní o di àjàwárí
Òrúnmìlà ní bi Òsun ba pa igba erukuku, orí re ni yio maa jàwá

Òrúnmìlà lo di àjàwárí
Moní o di àjàwárí
Òrúnmìlà ní bi Sango olukoso ba pa igba agbo, orí re ni yio maa jàwá

Òrúnmìlà lo di àjàwárí
Moní o di àjàwárí
Òrúnmìlà ní bi Obàtálá ba pa igba etú, orí re ni yio maa jàwá

Òrúnmìlà lo di àjàwárí
Moní o di àjàwárí
Òrúnmìlà ní bi osanyin mole lakodi ba pa igba ahun, orí re ni yio maa jàwá

Òrúnmìlà lo di àjàwárí
Moní o di àjàwárí
Òrúnmìlà ní bi òun èdú alájogun ba pa igba ideregbe, orí re ni oun yio maa jàwá

Moní Òrúnmìlà kaa mehùnrìn
Moní kilode ti o fi nfo bi èdè ti o fi nfo bi èyò?
Òrúnmìlà ní oun ko fo bi èdè, beeni òun ko fo bi èyò bi ki nse akápò toun ti won dafa fun
Moní toba je bi ti akápò tire ni nko, kini nkan to maa se to maa fi ja rori ayé re?
Òrúnmìlà ní ki won sofun akápò toun wípé ki o lo ni aporipo orí ewure, ki o ni sakiti aro ki o maa fi rubo, oni yio ja rori ayé re
Akápò kabomora o rubo won se sise ifá fun, lati igba naa ni akápò ti rori ayé re to ti de ibi ire re, o wa njo o nyo o nyin babaláwo awon babaláwo nyin ifá, ifá nyin Eledumare, oni nje riru ebo a maa gbeni eru àtùkèsù a maa da ladaju nje ko pe ko jina ifá wa bami ni jebutu ire, jebutu ire ni a nbawo lese obarisa.


AKOSE IFÁ NAA: Ao ki sakiti aro mo inu iho ori ewure nibi ti a ti yo obuntun re yen ti yio kun, ao fiyerosun tefa yi soju opon, ao ki ese ifá yi si ao se adura si daadaa ao bu iyerosun naa si gbogbo ara aporipo orí ewure naa, ao lo gbe soju atana(oju ona), tabi ki a beere ibiti a maa gbesi lowo ifá ti koba si oju ona ti a maa gbesi.
Eyin eniyan mi, mose ni ìwúre wipe Eledumare yio jeki a ja rori ayé wa o, eleda wa yio jeki a goke olá, orí ire ati igbega koni je eewo funwa, ao ri ona lo laye o aaasee.
ÀBORÚ ÀBOYÈ OOO.

About ayangalu

Viral Video

Support Ooduarere

SUPPORT OODUARERE
Scan QR code below to Donate Bitcoin to Ooduarere
Bitcoin address:
1FN2hvx5tGG7PisyzzDoypdX37TeWa9uwb
x

Check Also

Ìká Méjì ika meji

Ìká Méjì.

Ifa foresees a lot of Ire for the person this Odu is revealed to. He/she needs to offer Ebo so that Ase can be in his/her mouth.Ifa said if this Odu was revealed to a woman that is unable to conceive, the Babalawo will need to do Isé Ifá for her very well and the woman needs to stop eating groundnut so as for her to be able to conceive.And Ifa also made it clear that this person should always ...