Home / Art / Àṣà Oòduà / Ká ṣojú ẹni Ká sẹ́yìn ẹni Orúkọ tí à á pe ìránṣẹ́ (ìbò) .

Ká ṣojú ẹni Ká sẹ́yìn ẹni Orúkọ tí à á pe ìránṣẹ́ (ìbò) .

Òtítọ́ wọn kò sí láyé mọ́
Aṣẹ̀yìn deni wọn kò wọpọ̀
Àbàtà ńlá abojú dẹ̀gun dẹ̀gun
Ká ṣojú ẹni
Ká ṣẹ̀yìn ẹni
Àwọn mẹ́rẹ̀ẹ̀rin ní ọmọ ìkọ́fa
Ilé Àgbọnnìrègún
Baba kọ́won ní dídá ọwọ́
Wọ́n mọ̀ ọ́n dá
Ifá kọ́won ní títẹ̀ ilẹ̀

Wọ́n mò ọ́n tẹ̀
Baba kọ́won ní ìkarara ẹbọ ní híha
Wọ́n mọ̀ ọ́n ha
Wọ́n ń jẹ ìtí eku
Wọ́n ń jẹ ìtí ẹja
Wọ́n ń gba ẹyẹ
Wọ́n ń gba ẹran
Wọ́n ń jẹ ọ̀tọ̀tọ̀ ènìyàn lérù
Baba wá ní òun ṣ’awo lọ sí apá kan òkun
Òun ṣ’awo lọ sí ìlà mejì Ọ̀ṣá

Ódi ọdún mẹ́rìndínlógún kí òun tó darí dé
Òtítọ́ wọn kò sì láyé mọ́
Ni baba kó ewúrẹ́ fún pé kó mọ́ ọn tọ́jú
Aṣẹ̀yìn deni wọn kò wọpọ̀
Ni baba kó àgùntàn fún pé kó mọ́ ọn tọ́jú
Àbàtà ńlá abojú dẹ̀gun dẹ̀gun
Ni baba kó adìẹ òkòkó fún pé kó mọ́ ọn tọ́jú
Ká ṣojú ẹni
Ká sẹ̀yìn ẹni
Ni baba ko ẹyẹlé fún pé kó mọ́ ọn tọ́jú

Lẹ́yìn ọdún kẹrìndínlógún tí baba dé
Òtítọ́ wọn kò sì láyé mọ́
Eléyìun tí ba ewúrẹ́ jẹ́
Aṣẹ̀yìn deni wọn kò wọpọ̀
Eléyìun nì ba àgùntàn jẹ́
Àbàtà ńlá abojú dẹ̀gun dẹ̀gun
Eléyìun nì kó adìẹ òkòkó wọgbó
Ká ṣojú ẹni
Ká ṣẹ̀yìn ẹni
Eléyìun nìkàn ló tún ẹyẹlé ṣe

Òtítọ́ wọn kò sí láyé mọ́
orúkọ tí à á pe ìrọ́kẹ́
Ifá ní eléyìun kò gbọdọ̀ dá sí ọ̀rọ̀ tòun mọ́ láí láí
Tí wọ́n bá ń dá’fá
Kí wọ́n má a fẹnu rẹ̀ ṣẹpọ́n ko ko ko
Aṣẹ̀yìn deni wọn kò wọpọ̀
Orúkọ tí à á pe ìrùkẹ̀rẹ̀
Ifá ní eléyìun kò gbọdọ̀ dá sí ọ̀rọ̀ tòun mọ́ láí láí
Bí wọ́n bá ń dá’fá
Kí wọ́n kó má a fẹnu rẹ̀ gbáyẹ̀ròṣùn

Àbàtà ńlá abojú dẹ̀gun dẹ̀gun
Orúkọ tí à á pe ọpọ́n
Ifá ní eleyíun náà kò gbọdọ̀ dá sí ọ̀rọ̀ tòun mọ́
Tí wọ́n bá ń dá’fá
Kí wọn má a fọwọ́ lọ̀ọ́ nímú
Ká ṣojú ẹni
Ká sẹ́yìn ẹni
Orúkọ tí à á pe ìránṣẹ́ (ìbò)
Ifá ní ìbò nìkan ni kí ó má a dá sí ọ̀rọ̀ tòun ní gbogbo ìgbà

Ǹjẹ́ kínni ń bẹ lẹ́yìn tí ń tubọ?
Ìrànràn
Ìránṣẹ́ nìkàn ní ń bẹ lẹ́yìn tí ń tubọ
Ìrànràn
Ǹjẹ́ kínni yíò ma rànwá ṣe?
Ìrànràn
Ifá ni yóò ma a rànwá ṣe
Ìrànràn

Ifá yíò ma ṣe àrànṣe fún gbogbo Awo o!

– Ogbè Ògúndà (Ogbèyọ́nú)

About Awoyemi Bamimore

Viral Video

Support Ooduarere

SUPPORT OODUARERE
Scan QR code below to Donate Bitcoin to Ooduarere
Bitcoin address:
1FN2hvx5tGG7PisyzzDoypdX37TeWa9uwb
x

Check Also

Free Dele Farotimi | Seun Kuti