Àwo̩n S̩ó̩ò̩sì bè̩rè̩ ìjó̩sì l’Abuja lónìí
Yínká Àlàbí
O le ni osu meji bayii ti ijoba apapo ti fofin de Soosi ati Mosalasi. Ijoba ni ki onikaluku maa josin ni ile won, ijoba ni ko si ibi ti Olorun ko si ati wi pe Olorun sun mo wa ju isan orun wa lo.
Eyi lo mu ki gbogbo ile ijosin wa ni titi pa. Ijeeta ojo jimo, ojo karun-un, osu kefa yii ni ijoba apapo ni ki awon Mosalasi gbogbo ni ilu Abuja bere ijosin won pada. Koda Aare Mohammadu Buhari naa ba won kirun Jimo ni Aso Rock lojo naa.
Oni ojo keje, osu kefa yii kan naa ni ijoba ni ki awon Soosi bere isin won pada.
Gbogbo ofin ti ijoba apapo ati ajo NCDC gbe sile ni awon Mosalasi ati Soosi n tele koda awon elesin kirisiteeni ba de bi wi pe, won n foruko sile notori ti nnkan ti won ko ro ba sele, eyi maa rorun lati le to ile awon to josin ni ojo naa lo.